Lassa Fever, Corona Virus: Ṣé lílo ìbòjú tàbí ìbòmú lèé dènà kíkó àjàkálẹ̀ àrùn?

Ibomu Image copyright Getty Images

Nkan to wọpọ tẹẹ maa n saba ri nigba ti ajakalẹ arun kan ba bẹ silẹ ni ki awọn eniyan maa lo iboju tabi ibomu ko da titi fi kan awọn oniṣẹ ilera.

Wọn maa n lo o lati da abo bo ara wn dena kiko arun lawọn orilede gbajugbaja kaakiri agbaye paapaa ni bayii orilẹede China ti iṣẹlẹ arun Corona Virus ṣẹṣẹ bẹ silẹ bayii.

Ẹwẹ, awọn dokita onimọ nipa atanka arun ṣi n woye boya yoo wulo lati dena ajakalẹ arun naa to n gba ara afẹfẹ ran mọ awọn eeyan.

Bakan naa, arun iba Lassa to tun ti ṣẹyọ ni awọn ipinlẹ orilẹede Naijiria ti mu ki ọpọlọpọ oniṣegun oyinbo to n tọ ju awọn to ko arun naa atawọn to ba maa fi ara kan wọn maa bo oju ati ara wọn.

Ṣugbọn awọn iwadii kan ti fi han pe awọn iboju yii lee ṣeranwo lati dẹkun riran ka rẹ lati ọwọ si ẹnu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKí lo tíì rí nípa Amotekun? Ẹ sùnmọ́bí, ẹ wo gbankọgbì!
Image copyright Getty Images

Igba akọkọ ti awọn ile iwosan bẹrẹ si ni lo ibomu ni bii ipari ọọrundunrun kejidinlogun ṣugbọn wọn ko tii gbe e de itagbangba tawọn eeyan le maa lo afi igba ti ajakalẹa arun ti wọn pe ni Spanish flu bẹ jade lọdun 1919 eyi to pa eeyan to le ni aadọta miliọnu.

Dokita David Carrington ti fasiti St. George niluu London sọ fun BBC pe awọn iboju eyi ti wọn n ko fun awọn araalu ko lagbara to lati da abo bo wọn lọwọ awọn arun to n ba afẹfẹ kiri eyi si ni ọna ti ọpọ arun n gba tan kalẹ tori ko si ohunkohun to n da abo bo oju wọn.

Ṣugbọn awọn iboju naa le ṣi le mu adinku ba kiko arun lara ni to sin tabi wukọ o si lee da abo bo kiko arun naa lati ọwọ de ẹnu.

Iwadii kan ni ọdun 2016 ni New South Wales sọ pe awọn eeyan maa n fọwọ kan oju wọn ni igba mẹtalelogun laarin wakati kan.

Image copyright Getty Images

Dokita Connor Bamford ti Wellcome-Wolfson Institute for Experimental Medicine ni fasiti Queens ni Belfast sọ pe iṣe imọtoto bo ti wu o kere mọ n ṣiṣẹ takun takun.

O ni fun apẹrẹ "fifi ọwọ rẹ bo ẹnu ti o ba n sin, fifọ ọwọ rẹ ki o si ma ki ọwọ rẹ b ẹnu ki o to fọ wọn lee ṣeranwọ lati dena kiko arun.

O fi kun un wi pe bi o ko ba fẹ ko arun ti wọn n pe ni "flu":

  • fifọ ọwọ pẹlu ọṣẹ ati omi to lọwọrọ
  • ma fi ọwọ kan oju ati imu to ba ṣeeṣe
  • ati ki o maa gbe igbe aye ilera pipe.

Dokita mii ni England, Jake Dunning sọ pe iwoye kan tilẹ wa pe lilo inoju lee wulo ṣugbọn aridaju pe o n ṣiṣẹ to peye nita bi kii ba ṣe ile iwosan ko si.

O ni eeyan gbudọ lo iboju ni ilana to tọ, eeyan gbudọ maa parọ rẹ loorekoore ati bẹẹ bẹẹ lọ

Ẹwẹ ki eeyan gbajumọ imọtoto ara ẹni ṣe pataki gẹgẹ bi Dokita Dunning ṣe sọ ọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLáì rọ lápa rọ lẹ́sẹ̀, ẹ wo ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń lọ́ ara lóríṣi ọ̀nà

Lori awọn ipinlẹ Naijiria ti iba Lassa ti kọlu lẹnu ọjọ perete to pada de yii:

Image copyright Getty Images

Ibà Lassa bàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Enugu! Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ ọṣẹ́, Ẹ̀mí kan ti nù

Ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Enugu ti sọ pe aisan iba Lassa ti gba ẹmi eniyan kan ni ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo to wa nibẹ.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ṣe jabọ, Akọwe agba nileeṣẹ eto ilera naa sọ pe ẹni ti aisan naa pa jẹ iya agba ẹni ọdun marundinlọgọrin ti wọn gbe wa si ileewosan naa ni bi ọjọ mẹwaa sẹyin, pẹlu awọn apẹẹrẹ to jọ ti aisan iba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHepatitis: A kò leè kóo nípa dídìmọ́ ara ẹni

Ṣugbọn l'ọjọ Aje ni wọn lo bẹrẹ si ni pọ ẹjẹ l'ẹnu, eyi to mu ki wọn fura pe o ṣeesẹ ko jẹ iba Lassa.

Ayẹwo ti wọn ṣe ni ibudo ayẹwo ilera to wa ni Abakaliki ipinlẹ Ebonyi fi han pe aisan iba Lassa ni iya agba naa ni.

Ọjọru ni iya ọhun si jade laye.

Ọjọ Iṣẹgun ni iroyin kọkọ jade pe aisan naa pa eniyan mẹrin ni ipinlẹ Kano, ati pe o ti n ba wọn finra ni ipinlẹ Ondo naa bayii lakata ilẹ Yoruba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama