Valentine:Ọ̀nà ọ̀tọ̀ ni àjọ EFCC àti NYSC gbé àyájọ́ olólùfẹ́ ọdún 2020 gba

Yaaya ni awọn ọdọ to n sinru ilu tu jade lati polongo tako iwa ibajẹ layajọ ololufẹ Image copyright Twitter/officialefcc
Àkọlé àwòrán Yaaya ni awọn ọdọ to n sinru ilu tu jade lati polongo tako iwa ibajẹ layajọ ololufẹ

Ọna ara, ọna ọtọ ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni orilẹ-ede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commissin, EFCC gbe ajọyọ ayajọ ololufẹ ti ọdun 2020 gba.

Niṣe ni ajọ naa pẹlu awọn ọdọ to n sinrun ilu, awọn ẹgbẹ obinrin l'oriṣiriṣi, awọn ọdọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ rin jakejado Naijiria lati polongo tako iwa ibajẹ lawujọ.

Ṣaaju asiko yii ni ajọ EFCC ti kede pe ọwọ ifẹ ti awọn yoo na si awọn ọmọ Naijiria ni ayajọ ololufẹ ni lati polongo kaakiri pe ki awọn ọmọ Naijiria o jawọ ninu iwa ibajẹ pẹlu #YouthsWalkAgainstCorruption.

Ọpọlọpọ eniyan lo fesi si ikede ajọ naa lori ayelujara Twitter pe iyalẹnu ni yoo jẹ lati ri ajọ naa ko nawọ ifẹ yatọ si mimu awọn to n kowo ilu jẹ ati awọn ọmọ yahoo-yahoo.

Bayii ni ayajọ ololufẹ ajọ naa sẹ lọ kaakiri awọn ipinlẹ ni Naijiria.

Ipinlẹ Kaduna ati Plateau ko gbẹyin. Gomina ipinlẹ Plateau, Solomon Lalong naa darapọ mọ awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ati awọn agunbanirọ.

Koda, minisita fun ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya, Sunday Dare ati minisita fun ọrọ obinrin, Dame Pauline K Tallen naa kopa nibi eto naa nilu Abuja.

Ipinlẹ Adamawa naa ko gbẹyin nibi 'irin ifẹ' naa. Gomina ipinlẹ naa paapa darapọ mọ wọn.

Awọn ọdọ to n sinrin ilu naa tu yaaya jade nipinlẹ Eko lati kopa nibi akanṣe ayajọ ololufẹ naa.

Ipinlẹ Enugu naa ko gbẹyin pẹlu bi awọn ahunbanirọ ati gomina ipinlẹ naa, Ifeanyi Ugwuanyi ṣe darapọ mọ awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC.

Awọn ipinlẹ bi Oyo, Gombe, Kebbi, Bauchi, Cross River, Plateau, Delta, Edo, Osun, Ondo, Kwara, ati awọn ipinlẹ to ku lo kopa.