Lagos Fire: Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan bu ẹnu àtẹ́ lu bí ọjà ṣe n jóná l'Eko

Ina to n jo nile itaja lọja Balogun

Awọn ọmọ Naijiria kan ti n fi eero wọn han lori iṣẹlẹ ijamba ina to n waye lemọ-lemọ ni awọn ọja ipinlẹ Eko lẹnu ọjọ mẹta yii.

Eyi ribẹ nitori iroyin ijamba ina miran to tun waye ni ọja Apọngbọn, ni erekusu Eko ni owurọ ọjọ Aiku, botilẹ jẹ pe ohun to fa ina to jona ko ti i di mimọ.

Gbogbo akitiyan BBC lati ba alukoro ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nilu Eko, LASEMA, sọrọ lori iroyin iṣẹlẹ naa lo jasi pabo.

Igba akọkọ kọ niyi ti ina jo ni awọn ọja nla ni Eko l'opin ọdun 2019 si oṣu Keji ọdun 2020.

Lara awọn ọja ti ina ti jo ni ọja Balogun lẹẹmeji, isọpako Amu ni Mushin, ọja Mile 12.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBalogun Fire: Àwọn èèyàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣàlàyé ohun tó fa iná lọ́jà Balogun

Ibeere ti ọpọ wa n beere ni pe ki gan lo n fa awọn ina to n jo ọhun.

Diẹ lara nkan ti awọn eniyan n sọ ni pe o ṣeeṣe ki o jẹ pe awọn kan n sọ lori ayelujara ni pe bi awọn ṣọọbu to wa ninu awọn ọja nilu Eko ṣe fun mọ ara wọn lo ṣokunfa ina to n jo ni gbogbo igba.

Bakan naa ni awọn kan sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe awọn oniṣẹ ibi to fẹran lati maa dana sun dukia ẹlomiran lo wa nidi awọn iṣẹlẹ naa.

Awọn kan tilẹ gbagbọ pe ikọlu nla ni awọn ijamba ina naa jẹ si eto ọrọ aje ipinlẹ Eko.

Nigba ti awọn kan gbagbọ pe iwa aibikita awọn ontaja lawọn ọja naa lo n fa, ti wọn si sọ pe o yẹ ki ijọba o sowọpọ pẹlu awọn ọja kọọkan lati ri i pe ọna didana ijamba ina fẹsẹ mulẹ daada.

Related Topics