Coronavirus: Ìjọba Eko ti gbé èsì àyẹ̀wò ọmọ China tí wọ́n fura COVID-19 sí jáde

Ayẹwo fun aarun coronavirus Image copyright AFP

Ijọba ipinlẹ Eko ti fidirẹmulẹ pe ko si aarun coronavirus ni ipinlẹ naa, lẹyin ti ayẹwo fihan pe ọmọ orilẹ-ede China kan ko ni aarun COVID-19 naa.

Ọjọru, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2020, ni iroyin jade pe awọn alaṣẹ n ṣe iwadi ọkunrin naa nileewosan Reddington to wa ni Ikeja, lẹyin ti ọmọ orilẹ-ede China kan to pada de lati China laipẹ yii, gbe ara rẹ lọ sileewosan naa pẹlu awọn apẹẹrẹ kan.

Iroyin naa da ifoya si ọkan awọn eniyan, ṣugbọn awọn alaṣẹ ti sọ ni gbangba pe irọ ni, ati pe awọn ti n ṣewadi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn olúlùfẹ́ fí ìbòjú fi ẹnu ko ara wọn ní Philippine

Kọmisana eto ilera l'Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi sọ pe awọn ayẹwo ati iwadii ti wọn ṣe daada fihan pe ko si aarun coronavirus ni Eko lọwọlọwọ.

"Ninu iwadii wa, a gbọ pe ọmọ orilẹ-ede China kan to de si Naijiria lati China lọsẹ meje sẹyin lọ sileewosan lana, to si sọ fun wọn pe o n ṣe oun bi ibà.

Ileewosan naa tẹle amọran wa, wọn si taa ri rẹ si ileewosan Mainland to jẹ ibi ti a ya sọtọ fun awọn aarun.

Wọn ṣi ṣe ayẹwo ẹjẹ rẹ ni ibudo ayẹwo kokoro aarun. Esi ayẹwo naa fihan si fihan pe, ṣaka ni ara ọkunrin naa da."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌja Arena Oshodi ni àwọn èèyàn ti ń r'aja

Titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ajọ to n mojuto itankalẹ aarun ni Naijiria, Nigeria Centre for Disease Control, sọ pe igba eniyan mọkanla ti wọn furasi pe o ni aarun Coronavirus, ni wọn ti ṣayẹwo fun, gbogbo wọn ni ko si ni i.

Lọwọlọwọ, ọgọrin ẹgbẹrun eniyan, ni orilẹ-ede ogoji lo ti ni aarun naa, ti awọn kan si ti ku.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi'