Kaduna killings: Aṣojú-ṣòfin kan figbe ta pé kí ìjọba sán ṣòkòtò rẹ̀ gírí lórí ètò ààbò

Awọn eeyan to n sare lọ tori idarudapọ

Oríṣun àwòrán, Others

Eniyan ti ko din ni aadọta ni awọn agbebọn ti sekupa lasiko ikọlu to waye ni awọn abule kan nipinlẹ Kaduna ni asofin kan sọ.

Awọn alaṣẹ sọ pe, lootọ ni ikọlu naa waye ni abule Kerawa nijọba ibilẹ Igabi, ṣugbọn wọn ko sọ iye awọn to ba isẹlẹ naa lọ, ti ikọlu naa si tun mu ifarapa ba ọpọlọpọ eniyan.

Aṣoju-ṣofin kan, Zayyad Ibrahim sọ fun BBC pe, awọn agbebọn naa, to to ọgọrun yabo Kerawa ati awọn abule miran, lẹyin ti wọn kirun idaji tan lọjọ Aiku.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gomina ipinlẹ Kaduna Malam Nasurr El-Rufai

Bakan naa lo sọ pe, o ṣeeṣe ki awọn eeyan to ku to aadọta, ti awọn miran to farapa si n gba itọju lọwọ nile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo ti fasiti Ahmadu Bello, to wa nilu Zaria.

Ibrahim wa kesi ijọba apapọ lati dide iranlọwọ nipa fifi opin si ipaniyan to n waye lemọlemọ yika ipinlẹ naa ati lorilẹede wa Naijiria.

Àkọlé àwòrán,

Aworan atọka ibi ti ipinlẹ Kaduna wa ni orilẹ-ede Naijiria

Ipinlẹ Kaduna jẹ ọkan gboogi lara awọn ipinlẹ Naijiria to n dojukọ ikọlu lati ọwọ awọn agbebọn ati awọn ajinigbe pamọ gbowo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kaduna naa ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Agbẹnusọ wọn, ASP Mohamed Jalige sọ fun BBC pe, oun ṣi n duro de ẹkunrẹrẹ alaye lati ẹka ileeṣẹ ọlọpaa nijọba ibilẹ naa, ki oun to fesi.