Wasiu Ayinde: Ìrìnàjò ọdún kẹtàlélọ́gọ́ta rẹ̀ rèé, títí tó fi di Máyégún ilẹ̀ Yorùbá

Alhaji Wasiu Ayinde jẹ Mayegun

Oríṣun àwòrán, Instagram/K1 the ultimate

Àkọlé àwòrán,

Alaafin ilu Oyo fi Wasiu Ayinde jẹ Mayegun ilẹ Yoruba lọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2020.

Ọdun 1957 ni wọn bi gbaju-gbaja akọrin Fuji, Olasunkanmi Wasiu Ishola Anifowoshe, ti ọpọ eeyan mọ ọ si Wasiu Ayinde.

Ọdọ oloogbe Sikiru Ayinde Barrister ni Wasiu Ayinde ti bẹrẹ isẹ gẹgẹ bi ẹni to maa n ba ẹgbẹ akọrin rẹ ko irinṣẹ.

O ṣiṣẹ pẹlu ẹgbẹ akọrin Barrister, Supreme Fuji Commander, laarin ọdun 1975 si 1978.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Irinajo kan ti Barrister lọ si England lọdun 1974, ti gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ si duro de e la i ri nkankan ṣe, lo ru Wasiu Ayinde soke lati bẹrẹ ẹgbẹ akọrin rẹ.

Awo orin rẹ akọkọ to gbe jade, Iba, lọdun 1980, ko ta daada.

Ọdun 1984 to gbe awo orin miran to pe ni Talazo'84, ni ogo rẹ fi bẹrẹ si n tan kalẹ.

Àkọlé fídíò,

Wasiu Ayinde: Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá

Wasiu Ayinde ko pari ileewe girama ti ko fi lọ sileewe mọ nitori iku baba rẹ.

Ṣugbọn igbesẹ to gbe lati gba ileeṣẹ alamojuto onkọrin to fi ilu London ṣebugbe, Dayo Adekunle Olomu, D.O & Associates gẹgẹ bi manija rẹ, ṣeranwọ fun lati sọ orin rẹ di itẹwọgba laarin awọn ọlaju ati awọn miran ni agbo faaji Naijiria.

Awọn inagijẹ ti o wọpọ pẹlu Wasiu Ayinde ni:

Igi Jegede

Oba Orin

Kwam1,

K1 de Ultimate

Ipa ti Wasiu Ayinde ko ni agbo amuludun ni Naijiria ti mu ko jẹ oye loriṣiriṣi nilẹ Yoruba, to si tun gba ami ẹyẹ kaakiri agbaye.

Oríṣun àwòrán, Instagram/kwam1_official

Lara awọn oye naa ni

Badabarawu ilu Ogijo - 1985

Ekerin Amuludun ilẹ Ibadan - 1986

Golden Mercury of Africa Title - 1986

Oluomo ti ilu Eko - 1999

Oluaye Fuji Music ni NTA Ibadan - 1993.

Oluomo ilu Eko latọwọ Oba Adeyinka Oyekan ti Eko lọdun 1999

Ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2020, ni Alaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi kẹta fi Wasiu Ayinde jẹ oye Mayegun akọkọ nilẹ Yoruba.

Ọdun mọkanla sẹyin ni Wasiu Ayinde ti n dafun tolo si oye Mayegun ilẹ Yoruba, ki Alaafin to o jawe oye le lori l'ọdun 2020.

Awọn ami ẹyẹ bi i

Honoris Causa of Music at Saint John University Bakerfield California USA in 1989.

FAME Musician of the Year,

Best Fuji Artiste at the Nigerian Music Awards

Oríṣun àwòrán, Instagram/kwam1-official

Best African Artiste at the WOMAD Festival in Reading 1996

The Headies - Hall of Fame 2013

City People Lifetime Achievement Award - 2014

Wasiu Ayinde ti gbe ọpọlọpọ awo orin jade, bẹ ẹ si ni awọn eyi to kọ ni ode ere, sugbọn to gbe jade sori fọnran.

Lara wọn ni:

 • 1980: Iba
 • 1981: Esi Oro
 • 1982: Igbalaye
 • 1984: Talazo System
 • 1984: Talazo '84
 • 1984: Ise L'Ogun Ise
 • 1984: Ijo olomo
 • 1985: Talazo Disco 85
 • 1985: Alhaji Chief Wasiu Ayinde Barrister and His Talazo Fuji Commanders Organisation Oloriki Metta / Ki De Se
 • 1985: Elo-Sora
 • 1985: Pomposity
 • 1986: Ori
 • 1986: Tiwa Dayo
 • 1986: Erin Goke - Lecture
 • 1986: Baby Je Kajo
 • 1987: Talazo In London
 • 1987: Aiyé
 • 1987: Adieu Awolowo

Oríṣun àwòrán, Instagram/kwam1_official

 • 1988: Sun - Splash
 • 1988: Fuji Headline
 • 1988: My Dear Mother
 • 1989: Fuji Rapping
 • 1989: Achievement
 • 1990: Jo Fun Mi (Dance For Me)
 • 1991: American Trips
 • 1991: Fuji Collections
 • 1993: The Ultimate
 • 1995: Consolidation
 • 1995: Reflection
 • 1995: Talazo Fuji Party Music Compact Disk
 • 1996: Legacy
 • 1996: Faze 2 Global Tour '96
 • 1997: History
 • 1997: Berlin Compact Disk
 • 1999: Fuji Fusion (Okofaji Carnival)
 • 2000: New Era
 • 2000: Faze 3
 • 2001: Message
 • 2001: Statement
 • 2001: New Lagos
 • 2002: Gourd
 • 2003: Big Deal
 • 2006: Flavour
 • 2011: Tribute To My Mentor
 • 2012: Instinct
 • 2012: Fuji Time
 • 2017: 22 Dec Fuji Ep Let Music Flow