Super Tuesday: Ìdìbò láti yan ẹni tí yóò díje tako Trump bẹ̀rẹ̀

Super Tuesday: Ìdìbò láti yan ẹni tí yóò díje tako Trump bẹ̀rẹ̀

Ayajọ ọjọ ti wọn n pe ni 'Super Tuesdays' bẹrẹ jakejado ilẹ America ni imurasilẹ igbesẹ lati yan ẹni ti yoo dije pẹlu aarẹ Donald Trump. lati inu ẹgbẹ oṣelu Democrat.

Awọn oludibo jakejado ilẹ America ti n gbaradi lati kopa ninu ọjọ naa to jẹ to ti i tobi ju ninu idibo ọdun 2020.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ipinlẹ mẹrinla ni yoo dibo yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu Democrat ninu eto idibo aarẹ ti yoo waye l’oṣu Kọkanla. Bernie Sanders ni o n lewaju ninu awọn idije to ti kọkọ waye.

Ti yoo ba fi di Ọjọru, o yẹ ki ẹni ti wọn yoo yan ko fi oju han.

Ohun ti ayajọ Super Tuesday duro fun ninu idibo America ni iye atilẹyin ti oludije kọọkan ba ri gba ni ipinlẹ kọọkan ni yoo sọ boya oun ni yoo dije.

Afojusun ibẹ ni pe oludije kọọkan gbọdọ ni atilẹyin apapọ awọn aṣoju ipinlẹ kọọkan ti ko gbọdọ din ni ẹgbẹrun meji din mẹwa