Crime: Ọwọ́ ṣìnkún EFCC tẹ àfurasí ọmọ ‘Yahoo’ mẹ́fà n‘Ibadan

Posi oogun ti afurasi ọmọ Yahoo gbe lọwọ

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialefcc

Ọjọ gbogbo ni ti ole, amọ ọjọ kansoso pere ni ti olohun, bi irọ ba si lọ titi fun ogun ọdun, ọjọ kan soso bayii ni otitọ yoo baa.

Bẹẹ lọrọ ri fun awọn gende ọkunrin kan ti wọn fura si pe wọn n lu jibiti jẹun, taa mọ si ọmọ Yahoo, tọwọ palaba wọn segi nilu Ibadan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade kan ti ajọ to n gbogun ti iwa ọdaran nilu owona, EFCC fisita, loju opo Instagram rẹ salaye pe, awọn afurasi ọmọ yahoo tọwọ tẹ naa jẹ mẹfa niye.

Atẹjade naa ni adugbo Oluyọle ati Alao Akala ni ọwọ sinkun awọn osisẹ ajọ EFCC ti ba awọn afurasi ọmọ Yahoo naa, ninu eyiti obinrin kan wa laarin wọn.

Ohun to wa yani lẹnu nipa awọn afurasi ọmọ Yahoo yii, ni ti posi kekere kan, to jẹ apoti oogun abẹnu gọngọ ti wọn ka mọ mọ wọn lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialefcc

Inu ile ọkan lara awọn afurasi onijibiti naa, tii se ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ni awọn osisẹ ajọ EFCC ti ri posi oogun ọhun, to ni asọ funfun ninu, lasiko ti wsn ya bo ile rẹ lọjọ Aje to kọja.

Lasiko ti wọn fi ọrọ wa lẹnu wo lori ohun to n fi posi naa se, afurasi onijibiti naa ni igba ọsẹ ni ohun n lo posi kekere naa fun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialefcc

Lara awọn eroja ti EFCC ri gba pada lọwọ awọn afurasi onijibiti naa ni ọkọ ayọkẹlẹ mẹrin, ọpọlọpọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ olowo iyebiye ati aimọye kaadi ti wọn fi n gba owo lẹnu ẹrọ ATM.

"N kò jalè rí, ọtí àmuyó ló jẹ́ kí ń jí káàdì ìpè àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀"

Saaju la ti kọkọ sọ fun yin pe, ile ẹjọ Majistreti kan nipinlẹ Ebonyi ti ju ọkunrin ẹni ogun ọdun kan, si ẹwọn oṣu mẹta fun pe o ji kaadi ipe ẹrọ ibanisọrọ ati ẹrọ ibanisọrọ kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin naa sọ pe Elochukwu Sunday fi ipa gba ẹrọ ibanisọrọ alagbeka ati kaadi ipe lọwọ obinrin kan, Felicia Ezeaku, lẹyin naa lo tun gba ẹgbẹrun mẹrindinlogun naira lọwọ rẹ.

Wọn ni o ṣẹ ẹṣẹ naa ni adugbo Nkwogu nijọba ibilẹ Abakaliki nipinlẹ naa, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kinni ọdun 2020.

Eyi lo si mu ki wọn o gbe e lọ sile ẹjọ lẹyin ti ọwọ tẹ, wọn si fi ẹsun ole jija kan an.

Isipẹkitọ ọlọpaa to wọ ọ lọ sile ẹjọ sọ pe, ẹṣẹ to ṣẹ ni ijiya labẹ ofin iwa ọdaran ni Naijiria.

Ẹrọ ibanisọrọ naa ni wọn ni owo rẹ to ẹgbẹrun marun Naira, nigba ti kaadi ipe si to ẹgbẹrun mejila Naira.

Sunday jẹwọ pe, lootọ ni oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, ṣugbọn ọti ti oun mu yo lo mu oun hu iwakiwa.

"Mo jẹbi. Ọti amuyo lo mu mi hu iwa naa. Mi o jale ri. Idanwo lo jẹ fun mi, ẹ dakun ẹ darijimi."

Àkọlé fídíò,

Omidan jáde láyé lẹ́yìn tí ìlú lù ú, jáa sí ìhòhò lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀

Amọ ninu idajọ rẹ, Adajọ Majistreti Esther Ezeugo sọ pe ṣiṣe idajọ maa n rọrun ti ẹlẹbi ba ti bẹbẹ fun aanu.

Ẹbẹ Sunday lo si ni o mu ki oun dajọ ẹwọn oṣu mẹta fun un laisan owo itanran kankan.