Coronavirus: Èyí ni àwọn irọ́ bàǹtà-banta tí a ń pa fún ara wa nítorí Coronavirus

Ice cream Image copyright Getty Images

Awọn ibeere mẹta to yẹ ko bi ara rẹ ki o to pin iroyin nipa coronavirus niyii

Njẹ iroyin yii jọ jinlẹ, tabi o wa lati ọdọ ọrẹ ti mi o mọ ibi to ti wa?

Ri i pe o tu iṣu de isalẹ ikoko nipa ibi ti iroyin naa ti wa ki o to o pin - tabi ki o ma ti ẹ pin rara. Pe iroyin naa de ọdọ rẹ lati ọdọ ẹni ti o ni ẹmi igbagbọ ninu rẹ ko tumọ si pe awọn paapa ri iroyin naa gba lati ọdọ ẹni ti wọn mọ ri.

Ṣe gbogbo nkan to wa ninu iroyin naa jọ otitọ? Ọrọ ati alaye le pọ ninu iroyin naa, eyi si mu ki o rọrun lati gba a gbọ. Ọkan ninu awsn imọran naa le jẹ otitọ, ṣugbọn awọn to ku nkọ?

Ṣe iroyin naa mu inu rẹ dun, bi ọ ninu tabi mu ipaya ba ọ?

Ayederu iroyin maa n tankalẹ nitori pe wọn maa n ni ipa lori bi ihuwasi wa yoo ṣe ri. Nitori naa, iyẹn jẹ apẹẹrẹ pe o le ma jẹ otitọ.

Lẹẹkan si, ṣewadi to jinlẹ. Ọwọ awọn ajọ ati orisun to ṣe e gbẹkẹle bi WHO nikan ni iroyin nipa aṣeyọri lori itọju aisan naa, idena rẹ tabi ipolongo ati ikede, yoo ti jade.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNikesuliat: Ọ̀dọ́mọdébìnrin akéwì tó n fi ẹ̀ṣà kìlọ̀ ìwá lásìkò yìí

Wo àwọn irọ́ tí wọ́n ń pa fún ọ nípa àrùn Coronavirus

Ojoojumọ ni arun coronavirus n farahan si l'awọn orilẹ-ede kaakiri agbaye, ko si ti i si iwosan kankan to daju fun.

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe eyi ko fi opin si awọn imọran iwosan to lewu, ati awọn eyi to dara loju ṣugbọn to lewu.

A ṣe agbeyẹwo diẹ lara awọn iwasan ti awọn eniyan ti n polongo kiri, ati nkan ti imọ sayẹnsi sọ nipa wọn.

1.Galiiki

Ọpọlọpọ iroyin lo ti jade pe jijẹ galiiki, ti Yoruba n pe ni ata'lẹ lati dena arun ti gbale-gboko lori ayelujara Facebook.

Ajọ eto ilera l'agbaye, WHO, sọ pe lootọ ounjẹ aṣaraloore ni galiiki, to si le ni awọn eroja apa kokoro aifojuri ninu, ko si aridaju pe jijẹ galiiki le daabo bo awọn eniyan lọwọ arun tuntun coronavirus.

Lọpọ igba iru awọn iwosan bayii ko l''ewu, sugbọn wọn tun le fa wahala si agọ ara.

Iwe iroyin South China Morning Post gbe iroyin jade nipa obinrin kan to ba ara arẹ nileewosan lati gba itọju nitori pe ọfun rẹ wu ju boṣeyẹ lọ lẹyin to jẹ kilogiramu kan aabọ galiiki tutu.

Lootọ ni pe jijẹ eso ati ewe, ati omi mimu lu mu ki ara o jipepe, ko ti i si ẹri pe ounjẹ kankan le gbogun ti arun yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Àwọn ìlana to tọ̀nà lati tọ ti o ba fún pe o ni ààrun

2.Ọsẹ ipawọ apakokoro (Hand sanitiser) ti a ṣe nile

Awọn iroyin kan ti wa kaakiri pe ọṣẹ apakokoro ti wọn nigboro, botilẹjẹ pe fifọ ọwọ rẹ jẹ ọkan lara ọna lati dena itankalẹ arun naa.

Image copyright Getty Images

Iroyin ọwọn gogo ipawọ apakokoro ti mu ki oriṣiriṣi ọna lati ṣe agbelẹrọ rẹ ti wa kaakiri lri ayelujara.

Ṣugbọn awọn onimọ sọ pe awọn ko gbagbọ pe ẹnikan le ṣe ipawọ apakokoro to le dena aarun naa l'abẹẹle.

Ọpọ wọn si ni ko dara fun ara eniyan.

Image copyright Getty Images

3.Mimu omi niṣẹju mẹẹdogun mẹẹdogun

Iroyin kan ti ogunlọgọ eniyan ti pin kiri lori ayelujara Facebook ni pe "Dokita kan ni Japan'' sọ pe mimu omi laarin iṣẹju mẹẹdogun sira wọn dara lati fọ arun karun to ba gba ẹnu wọle jade.

Ṣugbọn Ọjọgbọn Trudie Lang ni Fasiti Oxford sọ pe "ko si ilana kankan" to faramọ fifi omi ṣan arun lọ sinu ikun rẹ lati pa a.

Inu ọpa to n gbe eemi ni arun bi coronavirus n gba wọ inu ara. Diẹ lara wọn si le wọ ẹnu rl, ṣugbọn omi mimu lera-lera ko ni i dena rẹ pe ko ma ni i.

Ṣibẹsibẹ, awọn onimọ nipa ilera sọ pe omi mimu dara fun ara rẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Galiiki dara fun ilera lootọ, ko le dena arun coronavirus.

4.Ooru ati yiyago fun ipanu 'ice cream'

Awọn kan ti ẹ n sọ pe ooru maa n pa arun naa, ti wọn si n gba awọn eniyan nimọran lati maa mu omi to gbona, wẹ pẹlu omi to gbona.

Iroyin kan to ti gbale-gboko kaakiri agbaye- ti wọn si sọ pe o wa lata ọwọ ajọ to n mojuto ilera awọn ọmọde l'agbaye.

Unicef-sọ pe mimu omi to gbona, ati diduro sinu oorun, to fi mọ yiyago fun 'ice cream' le pa arun naa.

Ṣugbọn, oṣiṣẹ ajọ Unicef kan, Charlotte Gornitzka sọ pe irọ ni iroyin naa.

Lootọ ni pe otutu ara kii ye l'ode ara lasiko ooru, sugbọn a ko le sọ ipa ti o le ni lara arun tuntun coronavirus.

Nitori naa, sisa ara rẹ sinu oorun, tabi mu omi gbigbona, ati wiwẹ pẹlu omi gbigbona ko le ran ọ lọwọ.

Ti arun naa ba ti wọ ara, ko si ọna lati pa a.

Coronavirus: Àsìkò ti tó láti tilẹ̀kun mọ àwọn alejo to ń wọ Naijiria- Ilé Asofin

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, ti ké si ìjọba àpapọ pe ki wọ́n fi sínú ìrònú wọ́n láti fi ofin de àwọn arinrin ajò ti kìí ṣe ọmọ Naijíríà láti àwọn orilẹ̀-èdè ti ààrun (COVID-19) náà n bá fíra láti ma wọ orilẹ̀-èdè mọ́.

Àkọlé àwòrán Coronaviru: Àsìkò ti tó láti tilẹ̀kun mọ àwọn alejo to ń wọ Naijiria- Ilé Asofin

Àwọn ọmọ ilé gba àbá ti Ibrahim Oloriẹgbẹ́ to jẹ́ alága ìgbìmọ lori ètò ìlera mu wá wọ́ lásikò ìjókó ilé.

Orílẹ̀-èdè Naijiria ti ri ẹni kẹẹta to tún ni àrùn Coronavirus lónìí ọjọ ìṣẹ́gun ti gbogbo rẹ̀ sì n tọka si orilẹ̀-èdè Italy àti UK ni bi tó jẹ́ àwọn agbègbè ti ààrun náà ti n ja fitafita.

Sááju ki wọ́n to ri ẹni kẹta yìí ni ìjọba apapọ ti sọ pe oun ko ni fofinde ẹnikẹni lati ilẹ̀ òkèrè to fi mọ àwọn ibi ti ààrun Coronavirus pọ sí

Oloriegbe wá fi kún pẹ lẹ́yin ti wọ́n ba fòfin dè wọ́n, kí àwọn Naijiria náà ko gbọdọ rìnrin àjò lọ si àwọn orilẹ̀-èdè ti ààrùn náà ti n ṣọṣẹ.

"Ti o bá ṣeeṣe kí àwọn ènìyàn máa rin irinajo lọ si àwọn orilẹ̀-èdè ti irú rẹ̀ ti n wáye, pàápàá jùlọ Yuroop nibi ti ọ̀pọ̀ àwọn orilẹ̀-èdè ti ba ààrun náà fíra, àyàfi ti ìrìnàjo náà ba ṣe pàtàkì jùlọ.

" o yẹ ki ijọba mọ pe kò yẹ ki wọ́n fi àye gba awọn tii ki ṣe ọmọ Naijiria láti wọle si orilẹ̀-èdè yìí. Bakan náà ni ki wọ́n túbọ ṣetò ààbo to gbóipọ̀n ni pápákọ̀ ofurufu.

"Àwọn ibudo máun péré ni Naijiria ni láti mojúto ààrun náà, o yẹ ki wọ́n náwọ ìrànwọ si àwọn ìpínlẹ̀."

Ààrẹ ilé ìgbimọ aṣòfin àgbà Ahmed Lawan gba abá ọhun wọle, o si fi kun pe o ṣe pataki ki àwọn ènìyàn tèlé òfin igbéle ọlọjọ mẹrinla ki wọ́n si lọ fun àyẹwo.

Related Topics