Taaooma Mariam Apaokagi: Ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú àwọn òbí mi yàtọ̀ sí bí mó ṣé n polongo nínú fídíò mi
Taaooma Mariam Apaokagi: Ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú àwọn òbí mi yàtọ̀ sí bí mó ṣé n polongo nínú fídíò mi
Ọdọmọde adẹẹrinpoṣonu, Mariam Apaokagi, ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Taooma ba BBC Yoruba ni alejo.
Ninu ọrọ to sọ, o sọ pe bi 'Iya Tao' ṣe maa n fọ oun l'eti ninu awọn fidio awada oun duro gẹgẹ bi ami idanimọ oun.
O sọ pe oun le ka iye igba ti iya oun ti na oun ninu ile.
"Koda, ti iya mi ba wo fidio mi nigba miran, o ma n sọ pe ha, o si n parọ ọ mọ mi.
Ko si ẹni ti ko ni iru eniyan ti iya Tao jẹ ninu ile gẹgẹ bi iya."