Mild symptoms of coronavirus : Kíni àwọn àmì nàá, àti ọ̀nà tí o le fi dáàbò bo ara rẹ?

  • By Pablo Uchoa
  • BBC Brasil
Imọran lori coronavirus

Bi aarun coronavirus ṣe n gbilẹ si ni gbogbo aye, lo n ṣekupa awọn eniyan.

Lọwọlọwọ, eniyan bi ẹgbẹrun mẹtadinlaadoje lo ti ku, ti miliọnu meji eniyan si ti ni aarun naa.

Awọn iwadii kan si ti fihan pe bi ìdá ọgọrin awọn to ni aarun naa ni ko ni fi ami rẹ han, tabi ni ami diẹ.

Bawo wa ni o ṣe le da ami coronavirus mọ?

Ẹdọfooro ni aarun Covid-19 maa n baaja. Ami meji gboogi to si maa n fihan ni iba ati ikọ ahugbẹ ti ko dawọ duro.

Ikọ ahugbẹ jẹ oriṣi ikọ ti ko mu kẹlẹbẹ jade, to si n ha eniyan ni ọfun, eyi ti eniyan si hu fun ọpọ igba laarin wakati kan, tabi fun bi igba mẹta laarin wakati mẹrinlelogun.

Eyi si le yọri si eemi ti ko ṣe deede.

Ki ọna ọfun o maa dun eniyan, igbẹ gbuuru, ara gbigbona, otutu, ati ori fifọ wa lara ami ti awọn eniyan tun ti sọ pe awọn n ri.

Ajọ eleto ilera l'agbaye, WHO, sọ pe aarin ọjọ mẹrinla ni aarun naa ma n lo ninu ara ko to fi ami han.

Kini o le ṣe ti o ba n ri ami?

Ọpọlọpọ awọn to ni covid-19 ni yoo gbadun lẹyin ti wọn ba fun ara ni isinmi, ati oogun ara riro (bi i paracetamol).

Ti o ba ni iba, ikọ, tabi idiwọ si bi o sẹ n mi, tọ ileewosan lọ, nitori eyi le jẹ pe aarun ti kọlu ẹdọfooro rẹ, tabi aisan miran to tun le.

Ajọ WHO sọ pe ki o kọkọ pe ileewosan rẹ na, wọn le dari rẹ si ibi to yẹ.

Igba wo ni o nilo lati lọ sileewosan?

Idi pataki ti awọn eniyan fi nilo lati ls sileewosan ni ti eemi wọn ko ba ja gaara.

Awọn dokita le ya aworan ẹdọfooro lati wo bi o ṣe gbọgbẹ si. Eyi to ba si le pupọ, wọn yoo da ẹni naa duro sileewosan, ni ẹka ti wsn ti n ṣe iranlọwọ fun eemi.

Wọn yoo si lo afẹfẹ atọwọda (oxygen) fun ẹni naa.

Fun awọn ti ilera wọn ba ti dẹnukọlẹ pupọ, wọn yoo lo fẹntilatọ lati fi gbe eemi wọ inu ẹdọfooro wọn ni taara lati ẹnu, imu tabi iho kekere ti wọn ba lu ni ọfun ẹni naa.

Taani ewu Covid-19 le wu julọ?

Awọn arugbo, ati awsn to ba ni aisan kan to n ba wọn finra ninu ara bi i ikọ semi-semi, itọ ṣuga ati aarun ọkàn, ni aarun covid-19 le da gunlẹ julọ.

Bakan naa ni aarun naa yara pa awọn ọkunrin ju obinrin lọ.

Bẹ ẹ si ni o le to ọjọ diẹ tabi ọsẹ melo kan ki ẹni to ba ni i to ni alaafia. Ṣugbọn awọn to ba wa nileewosan, tabi to n lo ẹrọ fẹntiletọ le lo to ọpọ oṣu ki ara wọn to o ya.

Bawo ni aarun naa ṣe buru to?

Abọ iwadii kan ti iwe atigbadegba imọ iṣegun oyinbo, The Lancet Infectious Diseases fi sita sọ pe ìdá 0.66% awọn to ba ni aarun naa ni yoo kú.

Ṣugbọn iyatọ le ba eyi nitori pe kii ṣe gbogbo awọn to ba ni aarun naa lo n sọ sita.

Bawo ni mo ṣe le daabo bo ara mi?

Igbesẹ pataki ni fifọ ọwọ loore-koore, paapa pẹlu omi ati ọṣẹ.

Aarun coronavirus maa n ran nipa ikọ tabi ikun ẹni to ba ni i.

Ẹlomiran le fa a simu, tabi ti o ba fi ọwọ kan ibi ti ikun tabi itọ naa ba bọ si.

Nitori naa, sisin tabi hihu ikọ si inu tiṣu, ki o ma fi ọwọ rẹ kan oju lai fọ, ati yiyago fun ẹni to ba ni aarun naa ṣe pataki.

Ti awọn kan ba ti n fi ami han ni wsn to o le ko ran ẹlomiran, ṣugbọn awọn miran le ko ran ẹlomiran ki o to o da wọn gunlẹ.

Awọn eleto ilera sọ pe lilo ibomu-bẹnu ko le daabo bo ọ patapata lọwọ Covid-19.

Ṣugbọn, ajọ WHO ṣi n ṣe iwadii boya lilo rẹ le ran awọn araalu lọwọ