How to wear facemask: Wo bí o ṣe le wọ ìbomú-bẹnu láti dènà Covid-19

Bi o ṣe le wọ ibomu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ti di ẹṣẹ bayii fun ẹnikẹni ti ko ba wọ ibomu-bẹnu laarin ilu l'orilẹ-ede Naijiria, nitori ofin ti ijọba ṣe lati fi dena itankalẹ aarun Covid-19.

Ọpọ eniyan lo si ti n tẹle ofin naa, ṣugbọn ti ọna ti wọn n gba lo ibomu naa kii ṣe ọna to tọ.

Wo ilana yii ni ṣiṣẹ n tẹle lati mọ bi o ṣe maa lo o:

Kọkọ fi omi ati ọṣẹ fọ ọwọ rẹ ki o si fi tiṣu nu u, tabi lo sanitaisa ki o to lo ibomu-bẹnu.

Oríṣun àwòrán, Wikihow.com

2. Yẹ ibomu-bẹnu naa wo boya ko ni aleebu kankan tabi ya.

Oríṣun àwòrán, Wikihow.com

3: Ibi to ṣaba maa n ni awọ buluu lara ibomu-bẹnu naa ni ki o jẹ ko kọju sita.

Ki ibomu-bẹnu naa le bo ọ daada, jẹ ki eti rẹ to dabi ẹni pe o le lọwọ diẹ wa ni oke imu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Wikihow.com

Lẹyin naa ni ki o fi okun ibomu naa kọ eti rẹ mejeeji. Ṣugbọn to ba jẹ okun gbọọrọ lo ni, so o mọ ẹyin ori rẹ.

Oríṣun àwòrán, Wikihow.com

Ti o ba ti ṣe bẹ ẹ, lo atanpako rẹ ati ika rẹ keji ti Yoruba n pe ni o dun-un labẹ lati fi fa a sita diẹ ni gongo imu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Wikihow.com

Ti o ba ti wọ ọ tan, ri i daju pe o bo imu ati ẹnu rẹ daada titi de abẹ àgbọ̀n rẹ.

Oríṣun àwòrán, Wikiho.com

Bi o ṣe gbọdọ bọ ibomu-bẹnu rẹ

Ma ṣe fi ọwọ kan inu ibomu-bẹnu naa nibi to ti bo imu ati ẹnu rẹ, nitori pe o le ti ko kokoro aifojuri lati ara eemi rẹ, tabi ti o ba hukọ tabi sin.

Àkọlé fídíò,

Coronavirus: 'Ewu ni tí Covid-19 bá wọ àdúgbò wa bí a ṣe fún pọ̀ yìí'

Okun rẹ ni ki o fi yọ ọ kuro ni oju rẹ.

Oríṣun àwòrán, Wikihow.com

Lẹyin naa ni ki o ju sinu ile idalẹsi loju ẹsẹ, ki o si fọ ọwọ rẹ. Ṣugbọn to ba jẹ pe ibomu-bẹnu ti o le lo ju ẹẹkan lọ̀ ni, bi i eyi ti wọn fi aṣọ ṣe, fọ ọ ni kiakia pẹlu omi gbigbona ati ọṣẹ, ki o si sa a sinu oorun.