Oral Sex: Àwọn tó kó àìsàn náà máa ń rí oje lójú ara wọn tó ń rùn bí ẹja

women dey get orgasm

Oríṣun àwòrán, Laurene Boglio

Iwadii ti fihan pe gbigba ẹnu ni ibalopọ lee pese ọna fun aisan oju ara obinrin ti oloyinbo n pe ni "bacterial vaginosis" tabi "BV" gẹgẹ bo ṣe jade ninu iwe iroyin atigbadegba PLos Biology journal.

O ṣeeṣe ki awọn obinrin to ko arun naa ma ri apẹrẹ ṣugbọn awọn mii yoo maa ri oorun to n bu tii jade pẹlu nkan to n jade lati oju ara wọn.

Awọn aṣewadii ti n toju bọ ọrọ yii lati mọ kini kokoro to wa ninu ẹnu nii ṣe pẹlu kokoro to wa ninu oju ara lasiko ti eeyan ba n gba ẹnu ni ajọṣepọ

Arun BV yii kii fi bẹẹ ṣe eyi to le to bẹẹ ṣugbọn o dara ki eeyan ṣe itọju ara rẹ to ba ko o toripe o maa n dakun bi obinrin ṣe le tete ko awọn arun ibalopọ STD ati UTIs.

Bi obinrin naa ba wa loyun pẹrẹ, o ṣeeṣe ko ṣokunfaa bibi ọmọ ti ko tọjọ.

Àkọlé fídíò,

Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Kini yii wọpọ, bẹẹ si ni awọn obinrin to ni aisan naa maa n rii pe oje to n jade lati oju ara wọn a maa run tuu bi ẹja.

O tun ṣeeṣe ki o rii pe awọ nkan to n jade ati kiki r ti yipada si bii awọ eeru ti ko funfun mọ bẹẹ si ni o maa ṣan.

Ẹwẹ, ogun antibiotics ti wa to lee wo aisan naa.

Ki ni abajade iwadii tuntun to jade yii?

Awan obinrin ti ko ni arun BV tẹlẹ ni kokoro iru eyi to dara fun agọ ara ti wọn n pe ni "lactobacilli" eyi to maa n mu ki oje oju ara obinrin duro deede ṣugbọn iduro deede yii naa le yẹ.

Ko tii si aridaju ohun to n fa a gan ṣugbọn bi o ko ba ṣọra, o lee ko arun BV bi o ba:

  • Bi o ba jẹ ẹni to fẹram ibalopọ gidi da ṣugbọn ko yọ awọn obinrin ti ko tii ni ibalopọ ri naa silẹ.
  • Bi o ba ni nkan idaabobo IUD.
  • Bi o ba maa n tẹ nkan to ni oorun lọfinda si agbegbe oju ara rẹ.
Àkọlé fídíò,

'Tíátà ọ́mọdé tí wọ́n ń kọ́ wa ní Bariga ti mú mi lọ Germany, Switzerland, Amsterdam...'

Iwadii inu Plos Biology fihan pe kokoro to wa ninu ẹnu lee fa aisan sara erigi ati eyin eyi to lee fa BV.

Wọn ti fi oju ara eeyan ati ekute ṣe sampu ayẹwo lati wo bi kokoro naa ṣe n huwa si lara ẹni.

Awọn ọmọwe to ṣe ayẹwo naa, Ọmọwe Amand Lewis kati fasiti California atawọn akẹgbẹ rẹ mii sọ pe iwadii yii ti ṣawarii bi gbigba ẹnu ni ibalopọ ṣe lee dakun iṣoro aisan BV.

Ọjọgbọn Claudia Estcourt to jẹ agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn onimọ ilera oyinbo alawọfunfun to nimọ nipa ibalopọ ati arun HIV sọ pe gbigba ẹnu ni ibalopọ tubọ maa n pin awọn arun ibalopọ kiri ni.

Àkọlé fídíò,

'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Báwo ni obìnrin ṣe ń ní ìtura ìbálòpọ̀? Wo àbọ̀ tí ọmọba kan, obìnrin àkọ́kọ́ tó ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ gbé jáde

Ọmọ ọba ni Marie Bonaparte, o lowo, o lọrọ, o gbajumọ, o tun mọ eeyan. Ṣugbọn bawo lo ṣe di gbajugbaja obinrin, to n ṣe iṣẹ iwadii lori ọrọ ibalopọ fun awọn obinrin?

Loju ọpọlọpọ, ọga ni ninu ka sọ ọrọ ibalopọ fun awọn obinrin. Fun awọn miran, olowo lasan, to mọ eeyan ni.

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES/LAURENE BOGLIO

Ṣugbọn otitọ to wa ninu ọrọ igbesi aye rẹ ni pe ibatan Emperor orilẹ-ede France, Napoleon I, to si tun jẹ anti fun Ọmọọba Philip, Duke ilu Edinburgh, jẹ ẹni kan ti itan ko le gbagbe rẹ lailai.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ ọba ni, ọkan lara awọn nkan to fi igbeaye rẹ lepa ni adun ibalopọ fun awọn obinrin.

Àkọlé fídíò,

Tantra: Ìlànà yìí ló ń kọ́ wa láti fi èémí àti ìṣẹ́po ara gbádùn ìbálòpọ̀

Mari gẹgẹ bi ọmọ ọba

Ọdun 1882 ni wọn bi Marie Bonaparte, nilu Paris, sinu idile to gbajumọ, to si lowo lọwọ. Ṣugbọn, lati kekere ni ibanujẹ ti wọ aye rẹ, nitori pe diẹ lo ku, ko kú lasiko ti iya rẹ fẹ ẹ bi.

O si ṣeni lanu pe, oṣu kan lẹyin ti wọn bi, ni iya rẹ ku. Eyi mu ki o danikan wa, nitori pe ko si ọmọde miran nile wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Marie Bonaparte ko ni ẹnikan a n ba a ṣere nigba to wa ni ọdọ, o si tun jẹ alagidi ọmọ

Lọjọ kan, ọkan lara awọn obinrin to n tọju rẹ ka a mọ ibi to ti n fun ara rẹ ni adun ibalopọ, eyi ti wọn n pe ni 'masturbation', ni ede Gẹẹsi.

Ha! Ni oni tọun pariwo, to si sọ fun pe "ẹsẹ ni! Nkan ti ko dara ni pẹlu! Wa a kú, to ba n ṣe e!"

Bayii ni Marie kọ ọ silẹ sinu iwe akọsilẹ rẹ lọdun 1952.

Onkọwe kan, Nellie Thompson, sọ ninu àyọkà kan to kọ nipa Marie pe "Bonaparte sọ pe oun dẹkun lati ma a fi ọwọ pa idọ oun fun adun ibalopọ l'ọmọ ọdun mẹjọ, nitori ibẹru pe ki o ma kú gẹgẹ bi wọn ṣe kilọ fun".

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Bo tilẹ jẹ pe ọmọọba ni, eyi ko ṣe idiwọ fun un lati ṣewadii ibalopọ fun awọn obinrin

O bẹrẹ si ni gbadun ibalopọ

Lẹyin to bi ọmọ meji fun ọkọ rẹ - ti wọn jọ gbe papọ fun aadọta ọdun - lo to o mọ pe ọnku rẹ, Ọmọọba Valdemar ti Denmark, ni ọkọ rẹ nifẹ si.

Eyi lo mu ki Marie pinnu lati pe afojusun oun yoo jẹ iwadii nipa ibalopọ fun awọn obinrin ati ọna ti wọn fi le jẹ adun rẹ.

Lọdun 1924, o tẹ akọsilẹ ọrọ kan jade nipa bi awọn obinrin kan kii ṣe ni imọlara adun tabi fihan pe wọn n gbadun ibalopọ.

Dipo rẹ, wọn ma n dibọn bi ẹni to n gbadun rẹ.

Ironu d'ori agba kodo wayii! Aye su u, nitori pe ko ni itura ibalopọ (orgasm) ri pẹlu nkan ọmọkunrin.

Kim Wallen to jẹ Ọjọgbọn nipa bi awọn eroja ara ṣe n ṣiṣẹ si ni Fasiti Emory, to wa ni Georgia America ṣe sọ fun BBC, Marie "ko gbagbọ pe nipasẹ idọ 'clitoris' nikan ni obinrin fi le ni itura lasiko ibalopọ".

Eyi lo mu ko gbe imọ ijinlẹ kan jade pe: bi alaafo to wa laarin idọ ati oju ara obinrin ba ṣe kere to, ni yoo sọ bi obinrin naa yoo ṣe ni itura si lasiko ibalopọ pẹlu nkan ọmọkunrin.Wo bí àwọn obìnrin kan ṣe n sọ ara wọn di 'fágìn' lẹ́ẹ̀kejì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Marie Bonaparte ati ọkọ rẹ, Ọmọọba George ti Greece ati Denmark

Lati gbe agbekalẹ rẹ lẹyin, obinrin to le ni 240 lo fi ṣe ayẹwo ni nkan bi ọdun 1920.

Bonaparte gbagbọ pe ti obinrin ba ṣe iṣẹ abẹ lati sun idọ rẹ mọ oju ara, itura ibalopọ 'orgasm' yoo wa.

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe, ko ri bo sẹ sọ.

Àkọlé fídíò,

Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èy

Ọjọgbọn Wallen sọ pe "òfo ọjọ keji ọja ni iṣẹ abẹ naa ja si. Diẹ lara awọn obinrin naa ko tiẹ wa a gbadun nkankan mọ nipa ibalopọ.

Eyi ko mu irẹwẹsi ba Bonaparte o, nitori pe o ni idaniloju pe imọ ijinlẹ rẹ kii ṣe otubantẹ, debi i pe ẹẹmẹta ọtọọtọ ni oun fun'ra rẹ ṣe iṣẹ abẹ naa. Ṣugbọn ko ri èrè kankan jẹ nibẹ.

Dokita Lloyd, to jẹ Ọjọgbọn nipa Itan ati ero ẹda ni Fasiti Indiana ṣalaye pe "ti o ba ge ọpọlọpọ isan kuro ni ara idọ obinrin, ara ko ni i gbe daadaa fun ibalopọ, nitori pe awọn iṣan to ṣe pataki lo n ge".

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obinrin to ni ominira

Yoruba ni bi a ṣe n dagba, la n gbọn si. Bi Marie Bonaparte ṣe n dagba si, mu ki o yi ero rẹ pada lori imọ ijinlẹ rẹ lori ibalopọ fun obinrin.

O si tẹ iwe tuntun kan jade lọdun 1950, to pe akọle rẹ ni 'Female Bonaparte', nibi to ti fagile gbogbo nkan to kọ nipa iwadii rẹ tẹlẹ.

Ọjọgbọn Wallen sọ pe "ninu iwe naa, o kọ ọ pe bi ara ṣe ri ko ni nkankan ṣe pẹlu itura ibalopọ, ati pe ọkan eniyan ni gbogbo ẹ wa".

Ni ero Ọjọgbọn Llyod, "eniyan takuntakun" ni Marie Bonaparte.