Independence Day Nigeria: Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwòrán mẹ́fà yìí ló dúró fún ọdún mẹ́wàá ìtàn ilẹ̀ wa

BBC Se akojọpọ itan nipa Naijiria pẹlu aworan mẹfa pere, eyi to n salaye awọn igba manigbagbe ninu ọgọta ọdun ti Naijiria gba ominira.

Bayii ni ẹgbẹ kan ṣe fi ijo ibilẹ da awọn eeyan lọla nibi ayẹyẹ ominira Naijiria lọdun 1960

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Bayii ni ẹgbẹ kan ṣe fi ijo ibilẹ da awọn eeyan lọla nibi ayẹyẹ ominira Naijiria lọdun 1960. Ọlọla Abubakar Tafawa Balewa gba akoso Naijiria ni kete tawọn oyinbo amunisin gbe ijọba silẹ tan, ti wọn si ta asia orilẹede olominira Naijiria soke ni ọjọ Kinni osu Kẹwaa ọdun 1960

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọdun meje lẹyin ominira Naijiria, ogun abẹ́le bẹrẹ lẹkun ila oorun, ti agbegbe Biafra si yapa. Ogun abẹle naa waye fun ọdun mẹta gbako, eyi to mu ẹmi eeyan bii miliọnu meji lọ, ti iyan ati ebi si pa ọpọ obinrin atawọn ọmọ wẹwẹ lẹkun ila oorun Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lọdun 1983 nijọba Shehu Shagari pasẹ pe ki miliọnu kan awọn eeyan ẹkun iwọ oorun Afirika, ti ọpọ wọn jẹ ọmọ orilẹede Ghana maa lọ silu wọn nitori ọrọ aje Naijiria to dagun. Awọn apo olokun tiirin, ti awọn alejo naa fi di ẹru wọn si ni wọn sọ ni Ghana Must Go, sugbọn wọn ti n lo ede ọhun fun awọn oloselu to n gba owo abẹtẹlẹ gọbọi, eyi to n ko ba ọrọ aje Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin ọdun mẹrindinlogun ti ijọba ologun fi dari Naijiria,eto iselu alagbada pada lọdun 1999. Ọgagun agba Abdulsalam Abubakar gbe ijọba kalẹ fun Olusegun Obasanjo, to bori ibo aarẹ. Saa ọdun 1990 yii si jẹ manigbagbe ninu itan Naijiria, to fi mọ bi wọn se wọgile ibo aarẹ ọdun 1993 ati isejọba Ọgagun Sani Abacha lọdun 1998.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ni ọjọ kẹrindinlogun osu Kọkanla ọdun 2001 ni awọn ọmọge kan dije fun idije omidan to dara julọ lagbaye, eyi to waye lorilẹede South Africa, ti ọmọge kan lati Naijiria, Agbani Darego si moke. Saaju akoko yii, awọn alawọ dudu kii saba kopa ni iru idije omidan bayii lagbaye, nitori wọn lee ma bori. Lasiko yii, orin ilẹ alawọ dudu ati ijo wọn lo gbode kan, ti awọn obinrin adulawọ si ti n ri ara wọn bii arẹwa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Losu kẹrin ọdun 2014 ni ikọ Boko Haram ji akẹkọbinrin to din diẹ ni ọọdunrun gbe lọ nilu Chibok lkun ariwa Naijiria. Bakan naa ikọ Boko Haram ti ji aimọye obinrin ati ọmọde gbe lọsaaju akoko naa. Ẹgbẹ kan to n pe fun idapada awọn akẹkọọ naa, ti Bukky Shonibare ko sosdi, lo n se iwọde pe ki ijba seranwọ lati ri awọn akẹkọọbinrin naa pada.