Fire accident victim: AbdulQudus Bello ṣàlàyé bí òun ṣe dí aláàbọ̀ ara nítorí pọpọ́ọ̀fù àti ìbínú jàǹdùkù àdúgbò

Fire accident victim: AbdulQudus Bello ṣàlàyé bí òun ṣe dí aláàbọ̀ ara nítorí pọpọ́ọ̀fù àti ìbínú jàǹdùkù àdúgbò

Fidio yii ni awọn aworan to le bani lẹru

Mi o wọ ẹwu ati bata ti mo fi de ile iwosan nigba ti mo gbọ- Iya Qudus

Ni Ilọrin ni iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ nibi ti Abdul Qudus to n ta pọpọọfu loju titi ti kagbako lọjọ naa.

O ni awọn janduku ati agbero maa n wa gbowo ita lọwọ awọn to n taja ati pe nigba mii wọn ko ni gba owo, wọn a fi gba pọpọọfu.

Abdulkareem Bello to jẹ iya Qudus ni oun ko wọ nkankan ti oun fi sa de ile iwosan General ti wọn gbe ọmọ oun lọ.

Alaba lati ile Salamaleku ni Ilorin ni wọn ni o fi ibinu da ororo gbigbona si Qudus nigba ti iyẹn ko tete fun un ni pọpọọfu oni igba naira to n beere fun.

Qudus royin ohun ti oju rẹ ri to nile iwosan ko to gbadun de ibi to de yii.

Bayii Alaba ile Salamaleku to da ororo lu Qudus ti wa ni atimọle ọlọpaa ni Ilorin ni ipinlẹ Kwara ni guusu Iwo oorun Naijiria.

Idajọ ododo ati iranlọwọ ni ẹbi Qudus n beere fun bayii.