NAFDAC pariwo ìbòsí aráàdúgbò síta lórí ayédèrú abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19 ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n mojuto akoso ohun jijẹ ati mimu lorilẹede Naijiria, NAFDAC ti ke gbajarw sita faraalu pe ayederu abẹrẹ ajẹsara COVID-19 ti wa lorilẹede Naijiria bayii.Oludari agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyẹye ṣalaye pe ajọ NAFDAC ko tii buwọlu abẹrẹ ajẹsara COVID-19 kankan, to si n kede pe ayederu abẹrẹ ajẹsara COVID-19 naa lee fa aisan to le ja si iku.O ni ajọ naa ko tii tẹwọ gba iwe igbayọnda kankan lati ọdọ awọn ileeṣẹ to n ṣe abẹrẹ ajẹsara naa.
- Dókítà 66 síṣẹ́ abẹ fún ìbejì tó lẹ̀pọ̀ nílé ìwòsàn fasiti Ilorin
- Àwọn agbébọn tó ń gba ojúgbó wọlé máa ń tó 1000 lẹ́ẹ̀kan náà - Amotekun
- Ẹ má ṣùn àṣùnpiyè o! Àwọn àjèjì darandaran ń wọ ìpínlẹ̀ Oyo àti Ogun lọ́gọ́ọ̀rọ̀ - Amotekun
- Ọ̀dọ́mọdé ẹni ọdún 38 ń figagbága pẹ̀lù bàbá ẹni ọdún 76 nínú ìbò Ààrẹ Uganda tó ń lọ lọ́wọ́
O fi kun pe ajọ NAFDAC yoo se ayewo daadaa lori eyikeyi ti wọn ba gbe jade nitori pe abẹrẹ ajẹsara tuntun ni to si nilo lati mọ boya yoo ni atunbọtan ibi kankan.
Oríṣun àwòrán, Min of health
Koko ohun ti ajo NAFDAC n sọ lori abẹrẹ ajẹsara COVID-19 ree
* Ajo NAFDAC ni awọn ko tii ri lẹta ẹbẹ igbayọnda lati ṣe abẹrẹ ajẹsara COVID-19 ni Naijiria.* Ko si ileeṣẹ tabi ajọ kankan to laṣẹ lati ko abẹrẹ ajẹsara COVID-19 wọ orilẹede Naijiria.* Ileeṣẹ yoowu to ba n po abẹrẹ ajẹsara COVID-19 to jẹ ojulowo gbọdọ gbe iwe ẹbẹ igbayọnda wọn tó ajọ NAFDAC wa.* Ko si ileeṣẹ tabi ajọ ijọba kankan to laṣẹ lati ko abẹrẹ ajẹsara COVID-19 wọ orilẹede Naijiria.
Dókítà tó lé ní ogún ní Covid-19 nílé ìwòsàn Fásitì Ilorin - Álága ẹgbẹ́ dókítà
Oríṣun àwòrán, Others
O ṣe e ṣe ki dokita to ni Covid-19 ni ileewosan ikọsẹ iṣegun oyinbo fasiti Ilorin, to ogun.
Alaga ẹgbẹ awọn dokita to n gba imọ kun imọ lọwọ (Resident Doctors) nilewosan naa, Dokita Abeeb lo fi iroyin naa sita, ninu ọrọ to sọ pẹlu ileeṣẹ akoroyinjọ Naijiria, NAN.
Ṣugbọn nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, alaga apapọ fẹgbẹ awọn dokita nipinlẹ Kwara, Ọjọgbọn Baba Awoye Isa sọ pe iye eeyan ti dokita sọ pe o ni Coronavirus nile iwosan naa, ṣe e ṣe ko to bẹ, tabi ju bẹẹ lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Ìpínlẹ̀ Oyo, Eko àti Ogun fọnmú lórí ìlànà pínpín abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
- Èèrà kò gbọdọ̀ rin Mattew Kukah ní Sokoto, ẹ má halẹ̀ mọ - Ìjọba àpapọ̀
- Seyi Makinde ní ọwọ́jà Covid-19 kò rinlẹ̀ bí NCDC se kéde èèyàn 120 tó ní àrùn lọ́jọ́ kan l‘Oyo
- Njẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àríyá oníhòhò àti ìbálòpọ̀ tó fẹ́ wáyé ní Kaduna lásìkò ọdún?
- Ìjọba gbé ilé ijó oníhòhò tì pa lórí ẹ̀sùn títàpá sí ìlànà àti dẹ́kun coronavirus
- Ilé aṣòfin Amẹ́ríkà yọ ààrẹ Donald Trump nípò fún ìgbà kejì
- Ìdí mẹ́fà rèé tí Instagram, Facebook le fi wọ́gilé ojú òpó ìkànsíraẹni rẹ
- Ìdí tí àwọn èèyàn kan kò fí le ni àrùn Coronavirus
O ni idi ni pe kii ṣe lati inu akọsilẹ ẹgbẹ dokita nipinlẹ naa, lo ti ri iye eeyan to darukọ.
O ṣalaye pe yatọ si awọn Resident doctors, awọn dokita wa ni awọn ẹka miran nileewosan naa, ati awọn ileewosan mii to wa nipinlẹ Kwara.
Coronavirus tips: Kìí ṣe gbogbo ìbòmù ló ń dá coronavirus dúró
O ni awọn ṣi n ṣe akojọpọ iye awọn dokita to ti ni arun naa nipinlẹ Kwara, nitori naa ni oun ko fi le sọ boya o to ogun tabi o ju ogun lọ.
Ọjọgbọn Isa gba awọn dokita ẹgbẹ rẹ nimọran pe ki wọn o ra awọn eroja idaabobo fun lilo wọn nileewosan, lati fi kun eyi ti ijọba ati awọn to gba wọn siṣẹ n fun wọn.
O fikun ọrọ rẹ pe, ijọba Kwara n gbiyanju lori amojuto aarun naa, ati ipese nkan itọju fun awọn to ni i.
O ni eyi ko ṣẹyin bi aarun naa ṣe lewu fun wọn, gẹgẹ bi ẹni to wa ni oju ogun aarun Covid-19.