Alaafin: Oluwo àti Sunday Dare sọ irú ẹ̀dá ti Aláàfin jẹ́

oluwo ti ilu Iwo ati Alaafin

Oríṣun àwòrán, Instagram/Oluwo/Alaafin

Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti ki Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla ku oriire lilo aadọta ọdun loke eepẹ.

Oluwo wa ṣapejuwe Alaafin gẹgẹ bi baba fun gbogbo ọba nilẹ Yoruba.

O ni ẹni ti eeyan n fi igbe aye rẹ tọrọ ni Alaafin, to si jẹ ẹni ti eeyan gbọdọ kọ ọgbọn lọdọ rẹ.

"Ti gbogbo ọba ba le ṣe, alaafin jẹ ẹni to yẹ ki wọn o ma a lọ si ọdọ rẹ lojoojumọ, lati ma a gbọ itan nipa ilẹ Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Mo nifẹ baba laiṣẹtan, gẹgẹ bi ọmọ."

O wa gbadura pe ki Alaafin tubọ pẹ laye ninu ilera to peye.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Alaafin Oyo

Bakan naa ni Minisita fun idagbasoke awọn ọdọ ati ere idaraya ni Naijiria, Sunday Dare ti ki Alaafin ku oriire aadọta ọdun lori itẹ.

Ninu ọrọ ikini to fi sita, Ọgbẹni Dare ṣapejuwe Ọba Adeyẹmi gẹgẹ bi ẹni to n mu iṣọkan wa nilẹ Yoruba, to tun n gbe aṣa larugẹ.

O ni kii ṣe idagbasoke, iduroṣinṣin ati ilọsiwaju nikan ni asiko rẹ ti mu wọ ipinlẹ Ọyọ, amọ o tun mu ki iṣọkan, ifẹ ati ireti jọba ni ipinlẹ naa ati Naijiria lapapọ.

Wo ọ̀pọ̀ àṣeyọrí tí Aláàfin ṣe láti àádọ́ta ọdún tó ti jọba

Yoruba ni ariṣe larika, arika si ni baba iregun.

O pe aadọta ọdun ti Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta ti di Alaafin ilu Ọyọ, ko si ṣe e ṣe lati ṣami ajọdun naa lai tọka si diẹ lara awọn nnkan aritọkasi to gbe ṣe.

Ta ba ni ka maa ka ni eni, eji, ilẹ kun nidi ọpọ aseyọri ti Alaafin ti gbe se ori oye, amọ diẹ lara awọn aseyọri naa ree, se bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba.

Idasilẹ ipinlẹ Oyo tuntun:

Lasiko ti ipe jade lati da ipinlẹ Ọyọ silẹ lọdun 1975, ipa kekere kọ ni Alaafin ko, pẹlu ajọṣepọ awọn eeyan mii, to mu ki idasilẹ ipinlẹ Ọyọ, Ogun ati Ondo dohun.

Ipa to si ko ninu idagbasoke Naijiria lo mu ki Aarẹ ologun, Murtala Muhammed yan oun nikan gẹgẹ bi ọba lati ilẹ Yoruba, lati kọwọrin pẹlu rẹ lọ si ilu Mecca fun Hajj.

Yatọ si eyi, ijọba tun fun ni ami ẹyẹ apapọ, CFR, lọdun 1975.

Baba isalẹ fasiti to lo saa mẹta:

Oríṣun àwòrán, facebook/ alaafin of oyo

Lọdun 1980, ijọba apapọ yan Ọba Adeyemi Kẹta gẹgẹ bi Baba isalẹ akọkọ fun Fasiti ilu Sokoto, to ti di Uthman Dan Fodio University bayii, fun ọdun mẹrin.

Lẹyin to pari saa akọkọ naa, igbimọ alaṣẹ fasiti naa tun fi orukọ rẹ silẹ fun saa keji. Ijọba naa si fi aṣẹ si i.

Ko tan sibẹ o, wọn tun damọran saa kẹta fun, ti ijọba si tun fi ontẹ lu u bakan naa. O jẹ apapọ ọdun mejila ti alaafin lo gẹgẹ bi Baba'salẹ fasiti naa.

Iru eyi ko ti i ṣẹlẹ ri ninu iyansipo Baba'salẹ ni Fasiti kankan ni Naijiria.

O yan Aarẹ Ọna Kakanfo meji sipo

Ọba Adeyẹmi lo yan oloogbe, Oloye MKO Abiola gẹgẹ bi Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba l'oṣu Kinni, ọdun 1988.

Oun naa lo tun yan ẹlomii, Iba Gani Adams, lati rọpo Abiola lọdun 2017.

O ṣe idasilẹ ilana irinajo Hajj ti Naijiria n lo

Lọdun 1990, ijọba apapọ labẹ iṣakoso Ọgagun Ibrahim Babangida yan Ọba Adeyẹmi Olayiwola gẹgẹ bi Amiru Hajj, lati dari awọn musulumi ni gbogbo ipinlẹ mọkanlelogun to wa ni Naijiria nigba naa, fun irinajo Hajj.

Abajade aṣeyọri Hajj ọdun naa si lo duro gẹgẹ bi osuwọn ti wọn fi n wo aṣeyọri irinajo Hajj ni Naijiria titi di oni.

O sagbatẹru bi awọn ọba kan nilẹ Yoruba ṣe di ọba alade

Oríṣun àwòrán, others

Ṣaaju akitiyan Alaafin Adeyẹmi, awọn ọba kan nilẹ Yoruba kii de ade ilẹkẹ.

Amọ pẹlu akitiyan rẹ, awọn kan lara wọn di ọba to n de ade ilẹkẹ, ti wọn si gba igbega lori igbelewọn awọn ọba nipinlẹ Ọyọ, ati ni awọn ipinlẹ bi Ọṣun ati Ondo.

Lara wọn ni:

Onjo ti Okeho, Onitede ti Tede, Asẹyin ti Iṣẹyin, Timi ilu Ẹdẹ nigba kan, Ọba Oyelusi Tijani Agbaran II

Lọdun 1980 si 1981, Ọba ilu Kisi, Okere ilu Saki, ati Sabi ti Iganna gba igbega.

Baalẹ Ile-Ogbo di ọba, Olu ti Ile-Ogbo lọdun 1995, Olubu ti Ilobu nigba naa gba ade lọdun 1986.

Àkọlé fídíò,

Ọba Olutayọ: ìgbésẹ̀ Ọọni àti Alaafin ti ń mú ìṣọ̀kàn dé sáàrin àwọn Ọba Yorùbá

Alayegun ilu Ọdẹ-Omu, Akire ilu Ikire, Akirun ti Ikirun, Aree ti Ire, Olunisha ti Inisha (gbogbo wọn wa nipinlẹ Ọṣun) gba ade nipasẹ Alaafin.

Nipinlẹ Ogun, Ọba ilu Ipokia di ọba alade ilẹkẹ.

Koda, Alaafin adeyẹmi lo gbe ade le gbogbo wọn lori nilu ẹnikọọkan wọn

O ma n bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba ti ko se daadaa

Oríṣun àwòrán, @alaafinofoyo

Ọjọ ti pẹ ti Alaafin Adeyẹmi ti n kọ lẹta lati bu ẹnu ẹtẹ lu awọn igbesẹ ijọba ti ko dara, koda ko to o jẹ ọba.

Ni nkan bi ọdun 1960, yatọ si awọn ọrọ to ma n kọ nipa ara rẹ sinu iwe iroyin, o kọ lẹta lati bu ẹnu ẹtẹ lu bi ijọba ṣe n ṣe awọn olukọ, lẹyin to ri ọkan lara awọn olukọ to kọ nileewe, to wọ akisa aṣọ.

O tun kọ lẹta mii to pe ni Ominira awọn obinrin: Nkan ti ko wọpọ nilẹ Yoruba.

Ọpọlọpọ igba lo si ti kọ lẹta si awọn olori ijọba bi gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, lasiko ti Fayẹmi ba awọn mẹrindinlogun wi nipinlẹ rẹ, fun pe wọn ko fọwọsowọpọ pẹlu ijọba.

Lẹta ibawi ati ikilọ lori aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba ni lẹta naa.

Bakan naa lo ti kọ lẹta si Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto aabo nilẹ Yoruba, ninu eyi to ti sọ fun aarẹ pe ko fi opin si bi awọn kan ṣe n kọlu ilẹ Yoruba.