Lagos ENDSARS panel: Olùpẹ̀jọ́ mẹ́rin tako ọlọ́pàá SARS gba sọ̀wédowó 16.250m Naira

Alaga igbimọ naa, Doris Okuwobi lo pin sọwedowo fun awọn olupẹjọ

Oríṣun àwòrán, channels tv

Àkọlé àwòrán,

Alaga igbimọ naa, Doris Okuwobi lo pin sọwedowo fun awọn olupẹjọ

Igbimọ to n gbọ ẹsun ti awọn arralu fi kan awọn ọlọpaa SARS nipinlẹ Eko ti fun eeyan mẹrin ni sọwedowo owo to le ni miliọnu mẹrindinlogun Naira.

Nibi ijoko igbimọ naa to waye ni ọjọ Satide ni igbimọ naa ti fẹnuko pe eeyan mẹrin ninu awọn mẹfa to kagbako ifiyajẹni lọwọ ọlọpaa, lo ri ẹri fi gbe ẹsun wọn lẹsẹ.

Awọn mẹrin naa si ni wọn fun ni apapọ owo to jẹ 16,250,000 Naira.

Obinrin mẹta lara wọn gba miliọnu mẹwa, miliọnu marun-un, ati ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹdẹgbẹrin din mẹwa Naira.

Ẹnikan to jẹ ọkunrin laarin wọn gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira.

Alaga igbimọ naa, Onidajọ Doris Okuwobi lo pin sọwedowo naa fun wọn.

Àkọlé fídíò,

EndSars Protest:Ọ̀gá Àgba Ọlọ́pàá ṣàbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Eko lẹ́yìn ìfẹ̀họ́núhàn EndSars

Bawo ni igbẹjọ naa ṣe lọ?

Ẹni akọkọ lara wọn, Felicia Opara, ni ọdọmọbinrin to wa ninu fidio kan to gba ori ayelujara ni ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, lasiko iwọde Endsars.

Ninu fidio naa, o han pe awọn ọlọpaa fi iya jẹ ẹ ni agbegbe Surulere nipinlẹ Eko.

Ninu idajọ rẹ, igbimọ naa sọ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa tọrọ aforiji lọwọ ọmọbinrin naa.

Bakan naa ni igbimọ ọhun fun ni N750, 000, owo gba mabinu.

Ẹnikeji ni Tolulope Openiyi ti igbimọ naa fun ni miliọnu mẹwaa Naira.

Oríṣun àwòrán, Punch ng

Igbimọ sọ pe o ri awijare rẹ sọ to si fi ẹri ti i pe ọlọpaa kan, Jide Akinola, lo yinbọn pa ọkọ rẹ Olusegun, ni ọdun 2017.

Ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Sabo, ni Yaba ni ọlọpaa naa ti n ṣiṣẹ.

Igbimọ naa fidirẹmulẹ pe ko si ẹri lati ọwọ ọlọpaa, to tako ẹjọ ti obinrin naa ro pe ni ibudo ayẹwo 'check point' ọlọpaa ni wọn ti yinbọn pa ọkọ rẹ.

Bakan naa ni iwadii igbimọ naa fihan pe lootọ ni ileeṣẹ ọlọpaa mu oṣiṣẹ rẹ to yin ibọn, ṣugbọn wọn pada yọnda rẹ.

Eyi si lo mu ki igbimọ naa daba pe ki wọn o fi oju ọlọpaa naa wina ofin. Bakan naa lo tun damọran eto ẹkọ ọfẹ fun ẹyọkan lara awọn ọmọ oloogbe.

Ẹni kẹta to gba sọwedowo ni Blessing Omorogie Esanbor, ti wọn fun ni miliọnu marun-un Naira.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@followlasg

Iwadii igbimọ naa fihan pe lootọ ni ile ẹjọ ju ọlọpaa to fiya jẹ, Emaanuel Okujor, si ẹwọn ọdun mẹtadinlogun, amọ Blessing ti di alaabọ ara, to si tun nilo iṣẹ abẹ fun oju rẹ.

Ẹni kẹrin ni Tella Adesanya, to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba fun iṣẹ agbẹ.

Sọwedowo ẹgbẹrun lọnaa ẹẹdẹgbẹta Naira ni wọn fun.

Oríṣun àwòrán, @followlasg

Eyi jẹ owo itunu fun bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe fi si ahamọ fun ọjọ mẹta lọna to tako ofin, ti wọn si tun gbẹsẹ le ọkọ ayọkẹẹ rẹ lati ọdun 2018 titi di asiko yii.

Wọn tun gba owo lọwọ rẹ.

Bakan naa ni igbimọ naa tun daba pe ki ileeṣẹ ọlọpaa yọnda ọkọ rẹ fun ni kiakia.