Tinubu ṣàbẹ̀wò sí ilé olóògbé Yinka Odumakin lẹ́yin ikú rẹ̀

Bola Tinubu ati aya oloogbe, Joe Odumakin

Oríṣun àwòrán, The punch

Àkọlé àwòrán,

Bola Tinubu ati aya oloogbe, Joe Odumakin

Asiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bola Tinubu, ti ṣabẹwo si ile agbẹnusọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin to di oloogbe ni ọjọ Satide.

Awọn iroyin kan sọ pe ibudo iyasọtọ ti wọn ti n tọju awọn alarun Covid-19 ni ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo, LASUTH, lo ku si.

Tinubu ti kọkọ sọ ninu atẹjade kan lọjọ Satide pe ko si bi wọn o ṣe sọ itan iṣejọba awaarawa ni Naijiria lai darukọ Odumakin.

Nigba aye rẹ, Odumakin ma n bu ẹnu ẹtẹ lu Tinubu ati ọpọlọpọ oloṣelu ni Naijiria.

O ṣapejuwe Yinkan Odunmakin gẹgẹ bi akinkanju, olootọ ati olufọkansin to nifẹ awọn eeyan ẹya Yoruba, ati orilẹ-ede Naijiria.

Lara awọn ipa to ni Odumakin ko waye lasiko rogbodiyan 'June 12' lẹyin ti wọn wọgile idibo ọdun 1993.

O ni "bo tilẹ jẹ pe ero wa ko papọ lori eto oṣelu, ko si idi kankan fun mi lati ṣiye meji nipa otitọ to fi ṣe gbogbo nkan to ṣe.

Titi lai ni yoo si jẹ awokọṣe gẹgẹ ẹni to gbe iṣerere orilẹ-ede rẹ leke ju ifẹ ara rẹ lọ."