Kano: Èèyàn bíi 70 kàgbàkó nínú ìjàmbá iná ní ilé-epo kan ní Kano

Ile epo to n jona ni agbegbe Sharada Rinji, nijọba ibilẹ Gwale ni Kano

Awọn alaṣẹ nipinlẹ Kano ti fidirẹmulẹ pe lootọ ni iṣẹlẹ ijamba ina kan waye ni ilu Kano, eyi ti ọpọlọpọ eeyan ti farapa.

Iroyin sọ pe lasiko ti ọkọ agbepo kan n ja epo bẹtiro ni ile epo kan to wa ni agbegbe Sharada, ni ọkọ na gbina.

Kọmisanna fun iṣẹ ode, Alhaji Garba Idriss Unguwar Rimi sọ pe ẹbi awọn to ni ile epo naa ni bi ijamba ṣe waye .

O ni "gbogbo eeyan lo mọ pe ko ba ofin mu, lati ma a ja epo bẹtiro ni ọsan gangan, paapaa lasiko ti oorun ba mu ni Kano.

"Oorun to mu lo fa bi ina ṣe ṣẹ yọ."

Alhaji Rimi sọ pe araalu mẹtalelogoji, ati oṣiṣẹ pana-pana mẹjọ lo fi ara pa ninu ina naa.

Ṣugbọn, iroyin sọ pe o ṣe e ṣe ki awọn to farapa ju iye ti ijọba fi sita lọ.

Idi ni pe opopona nla ni ile epo naa wa, ti ọpọ eeyan si n kọja lasiko naa.

Wọn ti gbe awọn to farapa lọ si ileewosan Mutala Muhammad to wa nilu Kano.

Ẹnikan lara awọn to wa nileewosan sọ fun ileeṣẹ redio Freedom Radio pe o n rin lọ ni nakn ba oun bi ẹni pe wọn lẹ nkan mọ oun lati ẹyin.

"Gbogbo ẹyin mi ati apá mi lo jona. Koda, ẹsẹ mi naa jona."

Ẹlomii, Musbahu Rabi'u Yaro sọ pe ileewe ni oun ti n bọ, ki oun to ṣakiyesi pe ina ti bọ si oun lara. Ori ati ẹsẹ ni ina ti jo o.

Agbẹnusọ ajọ pana-pana nipinlẹ Kano, Nura Abdulkadir Maigida, sọ pe iwadii ti n waye lati mọ nkan to fa ijamba ina naa.