Buhari Oloto: Gbajúmọ̀ ọba tó lo sàá lágbo fàájì ìlú Eko fún ogójì ọdún ó le

Ebenezer Obey ati Buhari Oloto

Oríṣun àwòrán, others

Agba akọrin, Ajinhinrere Ebenezer Obey-Fabiyi ti ṣapejuwe iku ọba alaye kan nilu Eko, to ku laipẹ yii, Alhaji Buhari Oloto, gẹgẹ bi adanu nla fun oun.

Ebenezer Obey sọ pe iyalẹnu ni iroyin iku rẹ jẹ fun oun, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi alatilẹhin oun timọtimọ fun ọpọlọpọ ọdun.

Ọjọbọ ni iroyin iku Ọba Oloto, to tun jẹ gbajumọ nilu Eko, jade sita.

Nigba aye rẹ, oun ni Ọba alaye ilẹ Iguru, Aguda, Surulere nipinlẹ Eko.

Oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020 ni ọba naa pe ẹni ọgọrin ọdun.

Ninu oṣu naa paapaa ni wọn gbe ade le e lori gẹgẹ bi ọba.

Ta ni Buhari Oloto to doloogbe yii?

Bakan naa ni iroyin sọ pe oun ni ọba akọkọ to jẹ, ni Aguda-Surulere.

Awọn olorin bi oloogbe Sikiru Ayinde Barrister, to si tun jẹ ọrẹ pẹlu rẹ, Wasiu Ayinde, Ebenezer Obey, ati bẹẹ bẹẹ lọ, naa maa n ki i ninu awọn orin wọn nigba aye rẹ.

Àkọlé fídíò,

Gbajugbaja oṣere tiata, Bolaji Amusan fi hann wa bo se láyà to lori ètò ṣé o láyà.

Koda, Oloto jẹ ilumọọka lagbo faaji fun ọpọlọpọ ọdun.

Botilẹ jẹ pe a ko le sọ nkan to pa baba agba naa, iroyin sọ pe ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo, Lagos State University Teaching Hospital (LASUTH) lo ku si.

Àkọlé fídíò,

Bethel Baptist high school Kaduna: Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò

Obey, to wa ni orilẹ-ede United Kingdom lọwọlọwọ, sọ pe alẹ Ọjọbọ ni oun gbọ iroyin Ọba Oloto nilu London ti oun wa.

O ni: eyi to jẹ ibanujẹ nla fun oun, nitori pe oun padanu ẹnikan lara awọn ọrẹ oun timọtimọ, to tun jẹ ololufẹ oun fun ọpọlọpọ ọdun.

Àkọlé fídíò,

Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y

Obey ni "lati igba ti Oloto ti wa ni ọdọmọkunrin, ni oun ati ẹgbọn rẹ, Sogunro, ti ma n wa wo mi ti mo ba n patẹ orin ni Miliki Spot ni gbogbo ọjọ Aje ati Ọjọbọ ni nkan bi ọdun 1970.

Àkọlé fídíò,

Okunade Sijuwade: Ìfẹ́ tí Sarun tó súnmọ́ Ooni jù láyé ní sí í ló sọ ọ́ di abọ́bakú- Adeye

Ebenezer ni: "Koda, lẹyin ti Sogunro ku, Buhari ṣi maa n wá ."

O ni oun yoo ṣafẹri oloogbe naa pupọ nitori pe eniyan daadaa ni.

Àkọlé fídíò,

Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb