Custom: Ọta ìbọn ba ẹnìkan nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè àti ará ìlú kọjú ìjà síra wọn ní Yewa nípìnlẹ̀ Ogun

Awọn ọkọ ajọ aṣọbode ti wọn jo ni ina

Oríṣun àwòrán, Premiumtimesng.com

Ọrọ di ẹni ori yọ, o di ile nilu Ayetoro, ijọba ibilẹ Ariwa Yewa nipinlẹ Ogun lalẹ ọjọ Ẹti, nigba ti awọn ara ilu naa ati awọn oṣiṣẹ ajọ aṣọbode kọju ija si ara wọn.

Awọn iwe iroyin abẹle sọ pe wahala na mu ki wọn o dana sun ọkọ ajọ aṣọbode mẹta, ti ibọn si tun ba ọdọ kan nilu naa.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun awọn akọroyin pe ija naa bẹrẹ lẹyin ariyanjiyan kan to kọkọ waye laarin oṣiṣẹ aṣọbode kan ati araalu kan ti wọn lo jẹ afurasi onifayawọ.

Ọgbẹni Razak Adeyemi sọ fun awọn akọroyin pe 'wọn yanju ariyanjiyan naa, ti kaluku si ba tiẹ lọ'.

O ni lẹyin bi i wakati kan, ni ọkọ Hilux mẹrin, to kun fun awọn oṣiṣẹ aṣọbode, wọ ilu naa, ti awọn aṣọbode naa si bẹrẹ si ni yinbọn si inu afẹfẹ.

Àkọlé fídíò,

Asẹ́yìn, àwọn ẹbí olóògbé ṣì ń fomijé dárò àwọn tóṣìṣẹ́ 'Custom' yìnbọn pa nílùú Iseyin

Nkan ti awọn oṣiṣẹ aṣọbode naa ṣe la gbọ pe o bi awọn ọdọ ilu Ayetoro ninu, ti awọn naa fi kọju ija si wọn.

"Gbogbo igbiyanju lati da wọn lọwọ ibọn yinyin duro, lo jasi pabo. Niṣe ni wọn n yinbọn mọ awọn eeyan nigba ti awọn ọdọ koju wọn.".

Àkọlé fídíò,

Bethel Baptist high school Kaduna: Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò

Ẹlomiran to tun ba awọn akọroyin sọrọ, Ọgbẹni Nojeem sọ pe awọn oṣiṣẹ aṣọbode naa n yinbọn mọ awọn bi ẹni pe wọn paṣẹ fun wọn lati pa ilu naa run.

"Niṣe lo dabi i pe oju ogun la wa ni. Ti kii ba ṣe pe ọpọ awọn ọdọ wa ni ajẹsara, pupọ ni ko ba ti ku bayii."

Àkọlé fídíò,

Omi iké kan, l'èèyàn kan lè mu f'ọ́jọ́ mẹ́ta láì ro ti ekòló inú rẹ̀ - Ìlú Elega, Kwara

O ni ọpọ eeyan ni ọta ibọn awọn oṣiṣẹ aṣọbode ya aṣọ wọn pẹrẹpẹrẹ, ṣugbọn ọta ibọn ko raaye wọ inu agọ ara wọn, ayaafi ọmọkunrin kan ti wọn yinbọn mọ lẹẹmẹta."

A gbọ pe wọn ti gbe ọmọkunrin naa si ile itọju ibilẹ kan lati gba ẹmi rẹ la.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọjọ diẹ ti iru rẹ ṣẹlẹ ni Ibarapa nipinlẹ Ọyọ, eyi to mu ẹmi awọn eeyan kan lọ.

Àkọlé fídíò,

Gbajugbaja oṣere tiata, Bolaji Amusan fi hann wa bo se láyà to lori ètò ṣé o láyà.

Agbẹnusọ ajọ aṣọbode ni Area 1 Command nipinlẹ Ogun, Hammed Oloyede sọ fun awọn akọroyin pe iwadii ti bẹrẹ lori nkan to fa ija naa.

Àkọlé fídíò,

Iya Woli: Ẹ̀mí ìjókíjó, Wòó, Ṣọ̀kí, Wojú, Ṣàkùṣákù, One Corner...jáde!