Àwọn aráàlú fi ẹsẹ̀ fẹ́ẹ lẹ́yìn tí wọ́n bá òkú ọkọ, ìyàwó àti ọmọ márùn-ún nínú ilé kan ní Apomu ní ìpínlẹ̀ Osun

Adegbeoyega oyetola

Oríṣun àwòrán, twitter/Adegbeoyega oyetola

Gomina ipinlẹ Osun Gboyega Oyetola ti ba awọn mọlbi ti eeyan meje ku ninu wn kẹdun lori iṣẹlẹ laabi yi.

Bakan naa lo ni ki wọn bẹrẹ iwadii ni kiakia lati mọ ohun to ṣokunfa iku awọn idile yi.

Ni Apomu ni ijọba ibilẹ Isokan ni awọn eeyan meje ninu ẹbi kan ti ku iku ojiji lọjọ Iṣegun.

Ninu atẹjade kan ti kọmisana feto ilera ipinl Osun Rafiu Isamotu fi sita, o ni ijọba yoo ṣa gbogbo ipa r lati tu iṣu de isalẹ koko ọrọ yi.

Àlàyé rèé lórí nkan tó pa èèyàn méje nínú ẹbí kan ní ìpínlẹ̀ Osun

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun ti sọ pe eefin ẹrọ amunawa ni awọn furasi pe o pa eeyan meje ninu mọlẹbi ẹlẹni mẹjọ nipinlẹ naa.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Yemisi Opalola sọ fun pe awọn iwadii akọkọ ṣe tọka si pe o sẹ e ṣe ko jẹ pe mọlẹbi naa gbe ẹrọ amunawa sinu ile, ti eefin rẹ si pada pa wọn.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe oku awọn eeyan meje naa lọ si mọṣuari ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo ti OAU nilu Ile-Ife.

Bakan naa lo sọ pe ara ọmọ kan ṣoṣo to yè ninu ẹbi naa ti n balẹ nileewosan ti wọn gbe e lọ.

Ati pe ayẹwo ara awọn oku naa, autopsy, ni yoo ṣafihan nkan to pa wọn.

Ọjọ Iṣẹgun ni ariwo eemọ, iru kileyi gba ẹnu awọn eniyan to n gbe ni abule Elegbaata, nitosi Oke-Suna, nilu Apomu to wa ni ijọba ibilẹ Isokan, nipinlẹOsun, lẹyin ti mọlẹbi ẹlẹni meje kan ku iku kayeefi.

Iroyin sọ pe ẹnikan pere ni wọn ba ni aaye ninu ile naa, ti wọn si gbe lọ si ileewosan kan nilu Apomu fun itọju.

Àkọlé fídíò,

Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Iṣẹlẹ naa to waye ni owurọ ọjọ Iṣẹgun lo jẹ iyalẹnu fun awọn ara adugbo naa nigba ti wọn deedee ri oku mọlẹbi naa ninu ile wọn.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, obinrin kan ti ko si nile ọkọ mọ lo n gbe ile naa pẹlu awọn ọmọ rẹ mẹfa, ati ọrẹkunrin rẹ kan.

Ẹnikan ti jẹ aladugbo obinrin naa sọ fun awọn akọroyin pe ara fu awọn aladugbo nigba ti wọn o ri ki wọn o ṣi ilẹkun ile naa ni aarọ, eyi to mu ki wọn o fi ipa wọ inu ile wọn.

"Nkan ti a ri ba wa lẹru pupọ. Gbogbo awọn to sun ninu ile naa, ọkọ, iyawo, ati ọmọ marun-un lo ti ku. Ọmọ kan pere lo ṣi wa laye, ko ni okun tabi agbara lati sọ nkan to ṣẹlẹ fun wọn.

O ni ibẹru lo mu ki awọn ara adugbo naa o salọ, pe boya o sẹ e ṣe ko jẹ kẹmika oloro ti wọn kọkọ gboorun ninu ile naa lo pa awọn eniyan ọhun.

Àkọlé fídíò,

Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board'

"Awọn mẹjọ lo wa ninu ile naa. Ọkọ, iya, ati ọmọ mẹfa, ṣugbọn kii sẹ ọkunrin naa lo ni awọn ọmọ. Obinrin naa lo ni ile, amọ ọkunrin ọhun n gbe pẹlu rẹ, amọ oun naa ni ile si ilu naa."

"Ọlọpaa ni ọkunrin naa, ti orukọ rẹ n jẹ Saheed, o n ṣiṣẹ ni Apomu, botilẹ jẹ pe kii ṣe ọmọ ilu Apomu.

O ni koda, ọkan lara awọn ọmọ naa ṣẹṣẹ de lati ipinlẹ Eko ni ọjọ Aje ni.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin. O si sọ pe wọn ti gbe awọn oku naa lọ si mọṣuari ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo nilu Ile-Ife.

Bakan naa lo sọ pe iwadii ti n lọ.