Sunday Igboho vs FGN : Ọmọ Fúlàní kọ ní mí, mí ò sì pàṣẹ kí DSS kọlù ilé Igboho, Amòfin àgbà Malami ṣàlàyé niwájú iléẹjọ́

Sunday Igboho ati ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, Igboho instagram/bbc

Wamuwamu lawọn agbofinro duro nile ẹjọ ti wọn ti gbẹjọ ti Sunday Igboho pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lori ikọlu ti wọn ṣe sile rẹ ni Ibadan.

Lasiko igbẹjọ yi, agbẹjọro Sunday Igboho Yomi Aliyu SAN, tako iwe ipẹjọ tuntun ti agbẹjọro Abdullahi Abubakar fẹ gbe kalẹ niwaju adajọ.

Lẹyin ti adajọ gbọ atotonu awọn igun mejeeji, o pe fun isinmi ranpẹ ki o to gbe idajọ kalẹ lori iwe ẹjọ tuntun agbẹjọro fun olujẹjọ akọkọ, iyẹn amofin agba Naijirialẹyin igba to si gba ki wọn kọwe ipẹjọ tuntun yi pẹlu owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta Naira to ni ki Abdullahi san.

Agbẹjọro Igboho to n beere fun owo gba ma binu lọdọ ijọba ni idi ti awọn fi tako iwe ipẹjọ tuntun yi ni pe Minisista eto idajọ sọ pe ohun ko mọ nipa ikọlu ti wọn ṣe si ile Igboho.

O ni iwe ipẹjọ yi bakan naa ni wọn sọ sinu rẹ pe agbẹjọro agba orileede Naijiria ni oun kii ṣe ọmọ ẹya Fulani.

Adajọ Ladiran Akintola ti sunjọ igbẹjọ yi si ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2021.

Amọ o ni idajọ to wa nilẹ pe ki wọn ma ṣe dunkoko mọ Igboho tabi fọwọ kan akanti owo rẹ ṣi fẹsẹrinlẹ.

Ìgbẹ́jọ́ n tẹ̀síwájú lórí ẹjọ́ tí Sunday Igboho pe ìjọba àti DSS lónìí Mínísítà ètò ìdájọ

Igbẹjọ lori ẹjọ ti o n waye laarin Oloye Sunday Igboho ati ijọba apapọ ati ileeṣẹ ọlọpaa abẹnu tijọba apapọ tun tẹsiwaju nile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ loni Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2021.

Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ ni igbẹjọ kan waye, nibi ti adajọ ti paṣẹ fun ijọba Naijiria ati ajọ DSS pe wọn ko gbọdọ halẹ, tabi mu Sunday Igboho titi di ọjọ igbẹjọ miran loni.

Ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Oyo, to wa ni adugbo Ring-Road nilu Ibadan ni igbẹjọ naa yoo ti waye.

Oloye Igboho n pe ileeṣẹ DSS lẹjọ, to si n beere fun ẹẹdẹgbẹta biliọ̀nu naira (N500billion) owo gba maa binu lori awọn dukia rẹ ti wọn bajẹ lasiko ikọlu wọn si ile rẹ lọjọ kini oṣu keje ọdun 2021 pẹlu titẹ ẹtọ rẹ loju mọlẹ.

Bakan naa lo tun n fẹ ẹẹdẹgbẹta biliọ̀nu naira (N500billion) miran fun ẹmi eeyan meji ti wọn pa lasiko ikọlu naa.

Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, gba-gba-gba lawọn agbofinro kun gbagede ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ to wa lagbegbe Ring road nilu Ibadan.

Ati ọlọpaa, ati awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ agbofinro DSS lo kun ile ẹjọ naa ti wọn ṣi n reti ki ẹjọ naa bẹrẹ.