Fadeyi Oloro wà ní ìdúbúlẹ̀ àìsàn, ẹ jọ́wọ́ ẹ rànwá lọ́wọ́ - Foluke Daramola

Gbajugbaja oṣere Yoruba lati ọjọ pipẹ ni Fadeyi Oloro, o ni oun ti di Pasitọ bayii.

Gbajugbaja oṣerekunrin, Ojo Arowosafe, ti ọpọ mọ si Fadeyi Oloro wa lori idubulẹ aisan.

Akẹẹgbẹ rẹ, Foluke Daramola lo fi ikede naa sita ni Ọjọru, lori ayelujara Instagram rẹ.

Ninu fidio naa ni Daramola ti ṣafihan Fadeyi Oloro ninu ile rẹ.

Daramola sọ pe o ti pẹ diẹ ti agba oṣere naa ti wa lori idubulẹ aisan, amọ oun ṣẹṣẹ gbọ nipa rẹ ni.

O ni oun n fi asiko yii kesi gbogbo awọn ẹlẹyinju aanu lati dide iranlọwọ fun oṣerekunrin naa.

Ninu fidio naa bakan naa, ni Fadeyi Oloro fun'ra rẹ ti sọ pe ki awọn eniyan dide fun iranlọwọ oun.

Bo tilẹ jẹ pe ko sọ iru aisan to n ṣe lọwọlọwọ, o ni o ṣeeṣe ki alaisan to ba ri oluranlọwọ o ma ku.

Fadeyi Oloro sọ pe ki awọn eniyan ṣaanu oun, ki wọn o ma jẹ ki oun ku bayii.

Àkọlé fídíò,

Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babalawo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré - Fadeyi Oloro

Foluke Daramola tẹsiwaju pe ajọ alaanu ti oun da silẹ, PARA, yoo lo owo ti awsn eniyan ba fun lati fi tọju Fadeyi Oloro.

O ni awọn n wa olutọju, ti yoo ma a gbe pẹlu rẹ, ti yoo si ma gba owo oṣu.

Igba akọkọ kọ niyyi ti iroyin aisan jade nipa Fadeyi Oloro. Koda, lọdun 2019 , iroyin jade pe o ti jade laye nitori aisan nla kan to ṣe e .