Eniola Badmus 20 years on stage: Èèyàn àti ẹbọra ló péjù-pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ogún ọdún tí Eniola Badmus ti n ṣeré ìtàgé

Fathia Balogun, Mide Martins ati awọn mii

Oríṣun àwòrán, others

Gbajugbaja oṣerebinrin, eniola Badmus ti ọpọ eeyan tun mọ si Lefty tabi Senator Badosky, ti ṣe ayẹyẹ ogun sdun to bẹrẹ iṣẹ ere ori itage ni ṣiṣe.

Ayẹyẹ naa to wa ni agbegbe Lekki nilu Eko ni ọjọ kẹsan-an, oṣu Kejila, ọdun 2021.

Ọpọlọpọ awọn akẹẹgbẹ rẹ, awọn gbajumọ lawujọ ati awọn eeyan mii lo peju sibẹ.

Ayẹyẹ naa ni wọn pe akọle rẹ ni "Eniola Badmus 20 Years on stage".

Oríṣun àwòrán, Screenshot/prettymikeoflagos/instagram

Akọrin takasufe, David Adeleke Davido ati olorin Fuji, Wasiu Ayinde, lo fi orin da awọn alejo laraya.

Lara awọn oṣere to peju sibẹ ni Iyabo Ojo, Toyin Aimakhu Ajeyemi, Dayo Amusa, Bimbo Thomas, Yinka Quadri, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Pẹlu awọn aworan ati fidio to gba ori ayelujara, o daju pe ayẹyẹ naa dun pupọ.

Ohun kan to tun jẹ iyalẹnu ni pe awọn 'oku' tabi awọn ti a le pe ni ẹbọra naa ba wọn peju sibi ayẹyẹ naa.

Eyi ko ṣẹyin gbajumọ kan nilu Eko, Pretty Mike, to ko ọkunrin ati obinrin toto ogun niye, ti wọn si fi nkan funfun kun ara wọn, pẹlu awọn oriṣiriṣi nkan miran to mu wọn dabi oku, lọ sibi ayẹyẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/mediaroomhub

Niṣe ni pupọ ninu awọn to wa nibi ayẹyẹ naa dide lati fi foonu wọn ya aworan awọn oku naa.

Oriṣiriṣi awọn nkan iyalẹnu ni Pretty Mike ma n ko lọ sibi ayẹyẹ ti wọn ba pe e si.

O ti ko awọn alaboyun, awọn to wọ aṣọ igbeyawo, ati bẹẹ bẹẹ lọ, lọ si ibi ayẹyẹ ri.

Nibi ayẹyẹ yii bakan naa ni Eniola Badmus ti ṣe ifilọlẹ iwe to kọ.