Alexis Sanchez: Man Utd faramọ asorọ ẹwọn lori jibiti owo ori

Alexis Santes
Àkọlé àwòrán Santes jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu to n gbowo julọ ti yoo jin sọfin aisan owo ori

Agbabọọlu fun ikọ Barcelona tẹlẹ naa lo nkoju igbẹjọ lorilẹede Spain nitori bo se gbokiti ipakọ si owo ori sisan eyi toto miliọnu kan Euro.

Owo ori ti ko san yi wa lati ara owo adehun ti Sandes ri lori ẹtọ si aworan rẹ to se lọdun 2012 si 2013.

Nigba ti wọn fẹsun naa kan Santes, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, lọdun 2016, asoju rẹ ni atamatase agbabọọlu naa ti "bọwọ patapata" fun ofin, to si tun ti kede owo to wọle fun-un ninu adehun ẹtọ si aworan rẹ to se."

Sanches, ẹni to darapọ mọ Man Utd latinu ikọ Arsenal losu to kọja, ni iroyin kan nsọ kiri pe oun ni agbabọọlu to n gba owo julọ ninu idije liigi Premier , lẹyin ti wọn ti taa, to si n gba miliọnu mẹrinla Euro fun ọdun kan lẹyin ti wọn ba ti yọ owo ori.

Santes nikan kọ lo jin si panpẹ ofin owo ori

Sanches yi si jẹ ọkan lara awọn gbajugbaja agbabọọlu to ti ko si panpẹofin owo ori lorilẹede Spain.

Losu to kọja, Agbaarin fẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid, Luka Modric san owo toto miliọnu kan Euro lati san owo ori nidi owo to ri latara ẹts si aworan rẹ to se.