Arsene Wenger: Awọn ọmọ ilẹ gẹẹsi maa nbẹ lori papa

Dele Alli ti gba'we ibawi ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Liverpool
Àkọlé àwòrán,

Wenger ti dẹnu ẹtẹ lu awọn ọmọ agbabọọlu ilẹ gẹẹsi

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Arsene Wenger ti dẹnu ẹtẹ lu awọn ọmọ agbabọọlu ilẹ gẹẹsi wipe wọn maa n bẹ lori papa bi ọbọ, ti ọpọlọpọ si maa ndinbọ fun adari idije.

Ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, Dele Alli ti gba'we ibawi ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Liverpool ni ọjọ isinmi.

Wenger sọ pe: "Mo ranti pe awọn iṣẹlẹ nla ni o wa nibi nigbati awọn agbabọọlu ajeji ṣe bibẹ lori papa, ṣugbọn awọn ọmọ ilẹ gẹẹsi ti kọ fifo lori papa bayi ti wọn dẹ ti wa d'ọga ninu bibẹ lori papa bayi.

Àkọlé àwòrán,

Wenger: Emi kii sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu lati dinbọ lori papa

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal sọ ni osu kọkanla ọdun to kja wipe Raheem Sterling mọ bi wn se nfo lori papa lẹhin ti Arsenal fidirẹ'mi lọwọ Manchester City pẹlu amin ayo mẹta si ẹyọ kan.

Wenger, ti ẹgbẹ rẹ yoo koju Tottenham ni papa isere Wembley ni ọjọ abamẹta sọ pe: "Emi kii sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu mi lati maa dinbọ lori papa. A ni lati dẹkun iwa ibajẹ yi ninu awọn idije ere ninu EPL".