AWC: Naijiria fi goolu bẹrẹ idije

Awọn oludije n figagbaga

Oríṣun àwòrán, @wrestlingngr

Àkọlé àwòrán,

Idije ẹkẹ mimu ti ilẹ Afirika yoo wa si idaduro ni ọjọ kọkanla osu keji ọdun 2018.

Ukoro Peter ọmọ orilẹede Naijiria to n dije fun ere idaraya ẹkẹ mimu Greco-Roman oni iwọn kilo marundinlọgọta ti gbẹyẹ nibi idije ẹkẹ mimu ti ilẹ Afirika to n lọ lọwọ ni ilu Port Harcourt.

Iyalẹnu nla ni ami goolu ti ọdọmọdekunrin naa gba fun orilẹede Naijiria jẹ lẹyin to bori Omar Abdelazi ti orilẹede Egypy ninu ayo mẹrin ọtọọtọ.

Oríṣun àwòrán, @wrestlingngr

Àkọlé àwòrán,

Iroyin ayọ ni orilẹede Naijiria gba ni ọjọ akọkọ idije fun ere idaraya ẹkẹ mimu ti ilẹ Afirika

"Inu mi dun, ayọ mi si kun lori aseyori yii." Ni ọrọ to ti ẹnu rẹ bọ lẹyin to bori.

"Nkan ti ko see se akawe ni sugbọn nitoripe o jẹ ere idaraya ẹkẹ mimu Greco-Roman, mo gbadun rẹ pupọ nitori igbadun nla ni idije ere idaraya ẹkẹ mimu Greco-Roman maa n jẹ fun mi."

"Inu mi dun, mo si mọ wipe pẹlu ore ọfẹ Ọlọrun, mo lee di odu ninu rẹ."

Oludije fun orilẹede South Africa, Lu Shawn Leonico lo se ipo kẹta to si gba ami baba (bronze) lẹyin to fi ẹyin Linus Katujanda lati orilẹede Namibia balẹ ni ẹẹmẹrin ọtọọtọ.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Wrestling federation

Àkọlé àwòrán,

Orilẹede Naijiria pegede ni ọjọ akọkọ idije ẹkẹ mimu ti ilẹ Afirika to n lọ lọwọ ni ilu Port Harcourt

Ni ipele oniwọn ọgọta kilo, ami ẹyẹ baba (bronze) ni Ikechukwu Robinson ti orilẹede Naijiria gba lẹyin to fi ẹyin akẹgbẹ rẹ, Medhi Dheker balẹ ni igba mẹjọ ọtọọtọ.

Orilẹede Algeria lo lewaju ni ipele naapẹlu Ahmed Merikhi to lu Emadeldin Helmi Yakout ti orilẹede Egypy ni ayo mẹjọ si mẹta.

Ni idije tẹkẹ mimu ti awọn obinrin, Sunmisọla Balogun lati orilẹede Naijiria naa ja ewe olubori pẹlu bi o se gbo ewuro soju akẹgbẹ, Natasha Nabaina ti orilẹede Cameroun ni ami ayo mẹjọ si mẹrin ni ipele oni iwọn marundinlaadọrin kilo eleyi to fun orilẹede Naijiria ni ami goolu keji ni ọjọ akọkọ idije naa.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Wrestling Federation

Àkọlé àwòrán,

Orilẹede Naijiria ko mọ wipe nkan yoo tete se ẹnuure funwọn nibi nibi idije ẹkẹ mimu ti ilẹ Afirika

Oludije orilẹede Naijiria miran, Aina Ohida ni tirẹ bori Farida Arabi lati gba ami ẹyẹ baba ni ipele oni iwọn kilo mọkandinlaadọta (49kg) nigbati Zineb Ech Charki lati orilẹede Morocco gba ami ẹyẹ goolu lẹyin to ti ta ọmi ayo marun-marun sugbọn ti idajọ fi si ọdọ rẹ.

Orilẹede Naijiria tun gba ami ẹyẹ baba (bronze) kan lati ọwọ Esther Asaolu ni ipele oni iwọn mẹtalelogoji (43kg)

Nigba to n sọrọ lori titayọ awọn oludije orilẹede Naijiria, aarẹ ajọ ẹkẹ mimu lorilẹede Naijiria, Daniel Igali ni awọn oludije naa ti n sunmọ afojusun ajọ ọhun.

Idije ẹkẹ mimu ti ilẹ Afirika naa yoo wa si idaduro ni ọjọ kọkanla osu keji ọdun 2018.