Andre Ayew: Baba mi loni ki n pada si Swansea City

Andre Ayew

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Andre Ayew darapọ mọ agbabọọlu Swansea City ni osu kini, ọdun 2018

Andre Ayew sọ wi pe baba rẹ ti o jẹ agbabọọlu tolamilaaka tẹlẹri fun orilẹede Ghana ati ẹgbẹ agbabọọlu Marseille, Abedi Pele lo parọwa fun ohun lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Swansea City.

Ẹgbẹ agbabọọlu Swansea City na iye owo ti o to milliọnu mejidinlogun pọun lati ra Andre Ayew lọjọ ti katakara awọn agbabọọlu wa s'opin ni osu kini, ọdun 2018.

Ayew to jẹ ọmọ ọdun mejidinlọgbọn, sọ wipe inu baba ohun dun lọpọlọpọ bi ohun se pada wa si ẹgbẹ agbabọọlu Swansea City, ti o si fi kun un wipe, nigba to n fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ lọdun 2016, inu baba ohun ko dun.

Baba Ayew, Abedi Pẹlẹ loti gba ami ẹyẹ African player of the Year ti o si gba Ife ẹyẹ Champions League pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Marseille lọdun 1993.

O ṣeeṣe ki Ayew o pẹlu awọn agbabọọlu Swansea City ti yoo fẹsẹwọnsẹ pẹlu Burnley lọjọ abamẹta. Eleyi yoo jẹ osu mẹtadinlogun ti Ayew ti o fi South Wales silẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu West Ham.