Winter Olympics 2018 - Ikẹtalelogun iru rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Winter Olympics ti bere ni south korea
Idije ere idaraya ti Winter Olympics 2018 ti ẹlẹẹketalelogun yoo bẹrẹ ni Olu-Ilu South-Korea, Pyeongchang lọjọ kẹsan si ọjọ karundinlogbon osu keji, ọdun 2018 pelu otutu to lamilaaka julọ ni itan orilẹede naa.
Lasiko ti wọn n gbaradi fun idije naa, orilẹede South ati North Korea fọwọsowọpọ fun igba akọkọ, ti wọn si parapọ yan awọn obinrin ti yoo soju wọn fun ere idaraya Hockey, ninu idije naa.
Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images
Pyeongchang gbalejo lọjọ kẹsan si ọjọ karundinlogbon osu keji
Iroyin fi lede wipe gbajugbaja elere idaraya to le ni ẹgbẹrun mẹta ni yoo kopa ninu Winter Olympics fun ayẹyẹ ami irawọ (Medal) to le lọgọrun ninu orisirisi ere idaraya marundinlogun.
Fun ẹkunrẹrẹ lẹsẹlẹsẹ lori bi ere idaraya Winter Olympics naa se n lọ, ẹ le kan si ẹka iroyin BBCTV, Redio, gbogbo ẹrọ ayelujara ti BBC ati ti oju opo BBC Sports.
-
Akwasi Frimpong
- Ọjọ ori: Mokanlelogbon
- Orilẹẹde: Ghana
- Ere idaraya: Skeleton
Akwasi Frimpong ni oludasile ajo ere idaraya ere ori yinyin ilẹ Ghana,ti a mo si Bobsled and Skeleton Federation(BSF-Ghana) lodun 2016.
Elere ori papa ni Frimpong je tẹlẹ sugbọn ijakule eṣe ibi gigise rẹ mu ki o yan ere idaraya mi laayo.
o sunmọ ọdun mẹrin si mẹfa ki eyan to le jẹ akosemose nidi ere idaraya yi nito ri pe ere ayara bi asa ni. -
Sabrina Simader
- Ọjọ ori: Mọkandinlogun
- Orilẹẹde: Kenya
- Ere idaraya: Alpine Skiing
Simader, ti awọn molebi rẹ ko lo si Austria nigba ti o wa lọmọdun mẹta ni ẹni akoko ti yoo soju ilẹ Kenya nibi idije Winter Olympics.
Ọdun 2013 lo bere si kopa nibi idije oun.Lọdun 2016,o soju orilẹẹde rẹ nibi idije Winter Youth Olympics ni Norway.
Bi eniyan ba wa lori yinyin ti o’n ba ere lo ni wara wara...a ma dabi ẹni ti oyi oju nkọ.Ara rẹ yoo ma sẹ giri bi ẹyẹ to bo kuro ninu okun.Asikọ rẹ tide. -
Mialitiana Clerc
- Ọjọ ori: Mẹrindinlogun
- Orilẹẹde: Madagascar
- Ere idaraya: Alpine Skiing
Mialitiana Clerc bẹrẹ sini kọ nipa ere ori yinyin nigba ti o jẹ ọmọ ọdun mẹta ni ilẹ France.O di ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni osu kọkanla ọdun 2017,eyi to mu ko jẹ ọkan lara awọn oludije ti ọjọ ori rẹ kere julọ nibi idije naa.
-
Samir Azzimani
- Ọjọ ori: Ogoji
- Orilẹẹde: Morocco
- Ere idaraya: Cross-Country Skiing
Samir Azzimani kọkọ kopa ninu ẹka ere ori yiyin ‘alpine skiing’ ki o to wa sun kuro lọsi idi ẹka ere miran ti wọn npe ni ‘cross-country skiing.
-
Adam Lamhamedi
- Ọjọ ori: Mejilelogun
- Orilẹẹde: Morocco
- Ere idaraya: Alpine Skiing
Adam Lamhamedi ti baba rẹ jẹ ọmọ Morocco ti iya rẹ si jẹ ọmọ Canada se oun manigbagbe nigba ti o di ọmọ ilẹ Afrika akoko to gba ami ẹyẹ goolu nibi idije Winter Youth Olympic Games ni Austria lọdun 2012.
-
Moriam Seun Adigun
- Ọjọ ori: Mọkanlelọgbọn
- Orilẹẹde: Nigeria
- Ere idaraya: Kẹkẹ ori yiyin ‘Bobsleigh’
Seun Adigun loludasilẹ ikọ kẹkẹ ori yiyin ‘Bobsleigh team’ akọkọ fun orilẹẹde Nigeria.Ọun ni awakọ ikọ naa.
Saaju ni o je elere ori papa to kopa ninu idije asafogi ‘hurdles’ Summer Olympics lodun 2012 nilu London.
O dabi ala ni . .. Ko si ẹni to kopa ri ninu idije Winter Olympics lati orilẹẹde Nigeria.Inu wọn dun pẹ ala yi di mumuse. -
Akuoma Omeoga
- Ọjọ ori: Mẹẹdọgbọn
- Orilẹẹde: Nigeria
- Ere idaraya: Kẹkẹ ori yiyin ‘Bobsleigh’
Akuoma ni wọn npe ni “brakewoman” fun ikọ kẹkẹ ori yiyin ‘Bobsleigh’ akọkọ fun orilẹẹde Nigeria.
Bakanna lo jẹ osise a wa aye fun ni si ẹka ilera.
-
Ngozi Onwumere
- Ọjọ ori: Mẹridinlọgbọn
- Orilẹẹde: Nigeria
- Ere idaraya: Kẹkẹ ori yiyin ‘Bobsleigh’
Ngozi Onwumere je elere ori papa to ti soju orilẹẹde Nigeria ninu idije ere idaraya ilẹ Afrika lọdun 2015
-
Simidele Adeagbo
- Ọjọ ori: Mẹridinlogoji
- Orilẹẹde: Nigeria
- Ere idaraya: Skeleton
Lẹyin isinmi ọdun mẹsan fun ere idaraya,Simidele Adeagbo ni iwuri latari aseyori ikọ kẹkẹ ori yiyin ‘Bobsleigh team’ orilẹẹde Nigeria.
Adeagbo ni ọmọ orilẹẹde Nigeria ti yoo kọkọ kopa ninu idije ti wọn pẹ ni ‘’skeleton’
-
Connor Wilson
- Ọjọ ori: Mọkanlẹlogun
- Orilẹẹde: South Africa
- Ere idaraya: Alpine skiing
Connor Wilson kẹko gboye nipa itọju ẹranko ni ile ẹko fasity Vermont ni orilẹẹde Amerika.
-
Mathilde-Amivi Petitjean
- Ọjọ ori: Mẹtalẹlogun
- Orilẹẹde: Togo
- Ere idaraya: Cross-Country Skiing
Mathilde-Amivi Petitjean ti fi saaju jẹ okan lara ọmọ iko ere idaraya ori yiyin fun orilẹẹde France ki o to sun lati soju Togo ilẹ abinibi rẹ.
-
Alessia Afi Dipol
- Ọjọ ori: Mejilelogun
- Orilẹẹde: Togo
- Ere idaraya: Alpine Skiing
Pẹlu bi ko se tan mo ile Togo,Alessia Afi Dipol yan lati soju ilẹ naa.
O kọkọ kopa labẹ asia Togo nibi idije Winter Olympics lọdun 2014 ni ilu Sochi.
-
Shannon-Ogbani Abeda
- Ọjọ ori: 21
- Orilẹẹde: Eritrea
- Ere idaraya: Alpine skiing
Abeda to dagba silẹ Canada gbero lati jẹ agbaboolu afigi gba lori yiyin ‘ice hockey’ sugbọn awọn obi rẹ ni ere yiyo lori yiyin pẹlu opa onirin(skiing) ni yoo je ere idaraya to ye.
Oun ni ọmọ Eritrea akoko ti yoo soju orilẹẹde rẹ nibi idije Winter Olympics.
Mo mo wi pẹ ko wọpọ ki ọmọ orilẹẹde Eritrea ma kopa ninu idije bayi sugbọn awa ọmọ Eritrea jẹ ẹni to ni ife ilẹ wa lọkan.Ti wọn ba ri ti mo’n kopa ti mo si n se daada,inu wọn yoo dun
Ẹni to ni aworan:
Matthias Hangst/Getty Images, Dimitar Dilkoff/AFP/Getty Images, Francois Xavier Marit/AFP/Getty Images, Shaun Botterill/Getty Images, Christophe Pallot/Agence Zoom/Getty Images, Alexander Hassenstein/Getty Images, ALEXANDER KLEIN/AFP/Getty Images, Dean Mouhtaropoulos/Getty Images, Courtney Hoffos