Winter Olympics: Buhari ransẹ oriire sikọ Naijiria

Awọn oludije lati Naijira n yan pẹlu asia orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Naijiria n kopa fun igba akọkọ nibi idije ere idaraya asiko yinyin lagbaye, Winter olympics.

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ransẹ ayọ sawọn oludije ọmọ ilẹ Naijiria nibi idije ere idaraya olimpiiki ori yinyin, Winter olympics to bẹrẹ lọjọ ẹti nilu Pyeong Chang, lorilẹede South Korea.

Agbẹnusọ fun aarẹ orilẹede Naijiria lori ọrọ gbogbo to jọmọ iroyin lori ẹrọ igbalode ati ayelujara, Bashir Ahmad salaye wipe inu aarẹ dun lori bi orilẹede Naijiria se n kopa fun igba akọkọ nibi idije Winter Olympics ọhun.

Seun Adigun, Ngozi Onwumere, Akuoma Omeoga ati Simidele Adeagbo lati orilẹede Naijiria ni yoo maa kopa ninu idije kẹkẹ ori yinyin.

Awọn si ni oludije akọkọ lati ilẹ Afirika ti yoo maa dije nibi ere idaraya ori yinyin lagbaye ti wọn n pe ni Winter Olympics.

Oríṣun àwòrán, Getty Images/LOIC VENANCE

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Buhari ni iwuri nla ni Seun Adigun, Ngozi Onwumere, Akuoma Omeoga ati Simidele Adeagbo jẹ fun awọn ọdọ Naijiria

Aarẹ Buhari gbosuba fawọn ikọ Naijiria ti wọn n kopa ninu idije kẹkẹ ori yinyin 'bobsleigh'paapaa julọ bi wọn se di ikọ akọkọ lati ilẹ Afirika ti yoo maa kopa ninu idije ere idaraya ori yinyin lagbaye, Winter Olympics.

Aarẹ Buhari ni, oun nigbagbọ wipe ifẹ ilẹ baba ẹni, ifaraẹnijin ati itẹpamọsẹ awọn ọmọ Naijiria naa, ti mu wọn dide duro pẹlu asia orilẹede Naijiria ni South Korea.

O ni eyi yoo jẹ iwuri nla fun ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria yoku paapaa julọ awọn ọdọ.

"Mo n ki awọn ikọ oludije orilẹede Naijiria ti wọn dide pẹlu asia orilẹede Naijiria nibi idije ere idaraya ori yinyin lagbaye, Winter olympics to n waye lorilẹede South Korea. Mo ki Seun Adigun, Ngozi Onwumere, Akuoma Omeoga ati Simidele Adeagbo ku oriire pẹlu bi wọn se n fi orukọ wọn ati orukọ Naijiria lelẹ ninu iwe itan."