Ikọ agbabọọlu Ọsun United kede awọn agbabọọlu tuntun

Awọn agbabọọlu Ọsun united n ya fọtọ saaju ifẹsẹwọnsẹ kan

Oríṣun àwòrán, Tunde Shamsudeen

Àkọlé àwòrán,

Ọjọ ẹti ni ikọ Ọsun united yoo kede awọn agbabọọlu marundinlọgbọn ti yoo maa wọ asọ rẹ lọdun 2018

Ẹgbẹ agbabọọlu Ọsun United ti bẹrẹẹ igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ipin keji idije liigi saa ọdun 2018.

Gẹgẹbi ara igbaradi ọhun ni kikede ti olukọni ere bọọlu ikọ naa, Adebayọ Adesina, kede awọn agbabọọlu mọkanlelọgbọn ti yoo gba awọn ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti ẹgbẹ agbabọọlu naa yoo gba ni ipele asekagba igbaradi wọn.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, alukoro fun ẹgbẹ agbabọọlu Ọsun united, Tunde Shamsudeen salaye wipe ọjọ ẹti ni wọn yoo kede awọn agbabọọlu marundinlọgbọn ti yoo maa wọ asọ ikọ agbabọọlu naa ni ipin keji idije liigi saa ọdun 2018.

"Oniruru igbaradi lo ti waye. A ti gba ọpọlọpọ ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ pẹlu awọn ẹgbẹ agbabọọlu to lorukọ kaakiri orilẹede Naijiria ninu eyi si ni a ti n yọ awọn agbaọọlu to ku diẹ kaato kuro ki o to ku mọkanlelọgbọn ti a kede yii. Sugbọn sa o, lẹyin ti a ba ti yan awọn mẹẹdọgbọn to ku ni ipele asekagba igbaradi wa yoo wa bẹrẹ."

Ikọ agbabọọlu Ọsun united yoo kopa nibi ifẹsẹwọnsẹ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ẹkun iwọ oorun Naijiria ti yoo waye laarin ọjọ kejidinlogun si ikẹtalelogun osu keji ọdun 2018 ni ilu Ijọbu ode.

Orukọ awọn agbabọọlu mọkanlelọgbọ ti ikọ naa kede ni yi:

1. Nurudeen Lateef 2. Maruf Olasupo 3. Gift Nwokeke

4. Luqman Raheem5. Kola Adejumo 6. Hammed Aliu

7. Emmanuel Osigwe8. Michael Osemene9. Afolabi Olatunbosun

10.Tooki Taofeek 11. Izu Leonard 12. Ekene Azike

13. Daman Umaru 14. Victor Okeji 15. Damola Fakayode

16. Dare Olatunji 17. Segun Falana 18. Adam Rasheed

19. Chiderah Eze 20. Hakeem Olalere 21. Pelumi Olarenwaju

22. Mamud Akorede 23. Shamsudeen Idris 24. Ibrahim Shokunbi

25. Timothy Okunoye 26. Odunayo Ogunsuyi27. Adebambo Ademola

28. Abubakar Sheriff29. Abdulsalam Yusuf30. Hammed Rasheed

31. David Fadairo