Gomina Ambọde kede ọjọ idije Lagos City Marathon ọdun 2019

Awọn olukopa n sare Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun awọn oludije to kopa ninu idije ere onibusọ asam'omi ọlọdọọdun 'Lagos City Marathon'ti ọdun 2018

Gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode ti kede rẹ wipe satide, ọjọ kẹsan osu keji ọdun 2019 ni akọtun idije ere onibusọ asam'omi ọlọdọọdun ni ti wọn dape ni Lagos City Marathon yoo maa waye.

Lasiko to fi n sọrọ nibi idije ti ọdun 2018 to waye ni ilu Eko, gomina Ambọde ni ireti oun ni pe nigba ti yoo fi di ọdun to n bọ naa, ọmọ orilẹede Naijiria ni yoo gba ipo kini ninu idije naa.Ọmọ orilẹede France kan to n sare fun orilẹede Kenya lo gba ipo akọkọ ninu idije ti 2018 eyi ti o mu ki gomina ipinlẹ Eko o lọgun sita wipe asiko fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria pẹlu lati dide soke ki wọn si bẹrẹ si ni faksys ninu idije naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn oludije lati ẹku ila oorun Afirika lo pegede nibi idije ti ọdun 2018

"O ti su mi lati maa gbe ẹbun owo idije yii fun awọn oludije lati ila oorun ilẹ Afirika. Nibayii, ipinlẹ Eko yoo bẹrẹ eto ni pẹrẹu lati gbe awọn akọsẹmọsẹ olukọni ere sisa dide, a o si morilẹ ilu Jos. Lẹyin ọdun meji o din dandan ki awa pẹlu bẹrẹ si ni wọ sokoto kan naa pẹlu awọn oludije ẹkun ila oorun Afirika yii."

Bakanaa lo tun se ileri lati rii wipe, osuwọn idije naa gbe pẹẹli si niwaju ajọ to nse amojuto ere sisa lagbaye.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gomina Ambọde ni idagbasoke n de ba idije Lagos Marathon

Nibi idije ti ọdun yii, gomina Ambọde kede ẹbun owo tuntun fun awọn to gbe ipo akọkọ laarin awọn ọmọ orileede Naijiria to kopa nibẹ.

Ra ọtọ ti wọn fi kun idije ti ọdun 2018 ni yiya ti wọn ya idije oni kilomita mẹwa kan sọtọ fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria nibi idije ere onibusọ asamu'mi naa.

Kiprotich Abraham lati orilẹede France lo se ipo kini pẹlu wakati meji o le isẹju mẹtala, eyi si ni akoko to yara julọ ninu itan idije naa.

Awọn ọmọ orilẹede Kenya meji, Rony Kipkoeck Kiboss ati Benjamin Bitok ni wọn se ipo keji ati ikẹta ni sisẹ-n-tẹle.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kilomita mejilelogoji ni ere ije Lagos City Marathon

Ẹgbẹrun lọna aadọta dọla owo ilẹ Amẹrika ni ipo kini gba ti ipo keji ati ipo kẹta si gba ẹgbẹrun lọna ogoji dọla ati ẹgbẹrun lọna ọgbọn dọla ni sisẹ-n-tẹle.

Ọmọ orilẹede Naijiria, Iliya Pam to jẹ akọkọ laarin awọn oludije ọmọ orilẹede Naijiria nibi idije onikilomita mejilelogoji naa pari ere ije rẹ ni wakati mejo o le ogoji isẹju o si gba ẹbun owo miliọnu mẹta naira.

Sharubutu Philbus se ipo keji pẹlu wakati meji io le isẹju mẹrinleaadọta lati jẹ ẹbun owo miliọnu meji naira.

Kefas Williams ni ọmọ orilẹede Naijiria kẹta ti oun pẹlu si jẹ ẹbun owo miliọnu kan naira.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iye ẹbun owo kan naa lo wa fun awọ̀n olukopa lọkunrin ati lobinrin nibi ere ije naa.

Orilẹede Ethiopia lo tan bii itansan oorun laarin awọn obinrin ti o kopa nibi idije naa.Alemenesh Herpha Guta, Tigst Girma Getayechew ati Ayelu Abebe lo gbe ipo kini, ikeji ati ikẹta pẹlu ẹbun owo ni sisẹ-n-tẹle bẹẹ ti wọn si gba Ẹgbẹrun lọna ni ipo, gba ẹgbẹrun lọna ogoji ati ẹgbẹrun lọna ọgbọn dọla owo ilẹ Amẹrika ni sisẹ-n-tẹle.

O le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun awọn oludije to kopa ninu idije ere onibusọ asam'omi ọlọdọọdun 'Lagos City Marathon'ti ọdun 2018.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orilẹede Ethiopia lo tan bii itansan oorun laarin awọn obinrin ti o kopa nibi idije Lagos city Marathon ti ọdun 2018

Papa isire ilẹeewa to wa ni Surulere ni wọn ti bẹrẹ ti wọn si pari rẹ si Eko Atlantic city ni Victoria Island .

Lara awọn leekan-leekan to peju sibi idije naa ni minisita fun ere idaraya lorilẹede Naijiria, Solomon Dalung, minsita fun eto iroyin ati asa, Lai Mohammed, asoju ọgagun agba ileesẹ ọmọogun Naijiria, aarẹ ajọ elere bọọlu ni orilẹede Naijiria, Amaju Pinnick pẹlu asoju ijọba ilẹ GLLsi lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Paul Arkwright.