'Hary Kane ni ọjọwaju Spurs'

Olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham Hotspurs, Maricio Pochettino, ti sọ wipẹ ogbontagi agbabọọlu orilẹede Gẹẹsi ni, Hary Kane ni ọjọwaju ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Harry Kane scores Tottenham's goal in their 1-0 win

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Kane ni agbabọọlu keji to jẹ Arsenal ninu ere bọọlu mẹrin loriarawọn lẹyin Jimmy Floyd Hasselbaink to jẹ Arsenal laarin ọdun 1997 si 2001.

Pochettino sọ ọrọ yii lẹyin igba ti atamatase ikọ agbabọọlu Tottenham naa ti fi ori kan bọọlu wọ inu awọn Arsenal eyi to fun ikọ agbabọ̀ọ̀lu naa ni isẹgun lori arsenal ninu ere ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League ti wọn gba ni gbagede papa isire Wembley.

Hary Kane fo sọke ko to fori gba bọọlu wọ inu awọn Arsenal lẹyin isẹju mọkandinladọta ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa.

Esi ere bọọlu awọn ẹgbẹ agbabọọlu London mẹjẹji yi lo sọ Spurs si ipo kẹta ninu atẹ liigi Premiership ti orilẹede England.

Igbiyanju asọlẹ Arsenal, Petr Cech, lo dina gbogbo akitiyan awọn ọmọ ẹgbẹ Spurs lati fi kun ami ayo kan ọhun.