Mourinho: Amin ẹyẹ fun ihuwasi to dara tọ si mi

Steve Bennett (apa ọtun) to jẹ adari kẹ́rin n fa Jose Mourinho (apa osi) seyin nibi to ti n fehonu han lori papa

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán,

Mi o ki n se bayi mọ, mo ti yiwapada

Oludari agba fun ikọ Manchester United, Jose Mourinho ti sọ wipe o yẹ ki oun gba amin ẹyẹ fun ihuwasi to dara lori etile papa igbabọọlu.

Orisirisi igba ni wọn ti le Mourinho kuro lori papa lọ si isọ iworan fun itakurọsọ pelu awon adari bọọlu kẹrin laarin igba ti o ti n se adari awọn ẹgbẹ agbaboolu.

Ni bayi, Mourinho so wipe oun ti yiwapada, ti oun si je okan ninu awọn adari ẹgbẹ agbabọọlu ni Premier ligi ti iwa rẹ dara ju.

"Mi o sere mo, mo ma n gbaradi, inu mi si dun. Inu mi ko le sai ru soke, sugbọn mo n kora mi ni ijanu. A kii mọọ rin, kori ma ji"

" Orisirisi amin ẹyẹ lo wa, eni ti o sisẹ takuntakun ju losẹ, oludari ẹgbẹ to gbegba oroke ju laarin osu, orisirisi - o yẹ ki wọn fun oludari to huwa dardara julọ ni etile papa igbabọọlu, o si ye ki o jẹ awọn adari bọọlu kẹrin ni ko dibo yan iru ẹni bẹẹ. O dami lju wipe emi ni yoo gba amin ẹyẹ naa."

Wọn ti le Mourinho lọ si isọ iworan lẹẹkan ni saa ọdun yi, nigbati ikọ agbabọọlu Man U fagba han ẹgbeagbabọslu Southhampton ni ọjọ kẹtalelogun ni osu kẹsan odun ti o kọja. Adari Man U yi ni o lọ si ori papa nigbati o ku diẹ ki idije pari, ti o n gbiyanju ati sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọslu rẹ ki wọn duro deede ni ipo wan lori papa.

Siwaju si, o wipe "Mi o da wahala silẹ nigbakugba fun adari kerin ni etile papa ayafi kaadi pupa ti mo gba ni Southampton nigbati mo fi ẹsẹ sori papa bọọlu."

Manchester United to wa ni ipo keji ni ori tabili Premier ligi yoo fẹsẹwọnsẹ pẹlu ikọ Newcastle ni papa isere St James ni oni ọjọ isinmi. Idije naa yoo bẹẹrẹ ni aago kan ọsan kọja isẹju marundinlogun.