Sanchez kuna lati gba Man Utd l'ọwọ Newcastle

Matt Richie ati awọn akẹgbe rẹ́

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán,

Idunu subu layo fun Matt Richie ati awọn akẹgbe rẹ́

Nibi Ifẹsẹwonsẹ Newcastle ati Man Utd to waye lọjo aiku, Newcastle jawe olu bori pẹlu ami ayo kan.

Matt Ritchie lo gba bọọlu wọ inu awon lẹyin ti Dwight Gayle fi gigise gba bọọlu si ni nkan bi isẹju marun din laadọrin.

Sugbọn oun ti awọn ololufe ere bọọlu n so nipa re ni bi Alexis Sanchez ti sẹ kuna lati gba bọọlu wonu awon lẹyin igba to ge asole Newcastle.

Ami ayo merindinlogun ni Manchester City fi sagba Man utd bayi lori tabili idije Premier League.

Awọn eniyan o senu ku lati ba Sanchez wi lori ẹro twita.