CAF Champions League: Plateau Utd na Eding Sport pẹlu ami ayo mẹta si odo

Awọn agbabọọlu ninu idije CAF Champions League Image copyright Getty Images

Ẹgbẹ agbabọọlu to lami laaka julọ ninu bọọlu abẹle lorilẹede Naijiria, Plateau United ti bu ewuro s'oju Eding Sport lati orilẹede Cameroon pẹlu ami ayo mẹta si odo ninu idije CAF Champions League.

Iroyin fi lede wipe ẹgbẹ agbabọọlu Plateau United lamilaaka ninu ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni ilu Jos lọjọ aiku.

Balogun fun ikọ Plateau United, Golbeh Elijah ni o kọkọ gba bọọlu s'inu awọn fun orilẹede Nigeria ni igba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wa ni isẹju mọkandinlogun, ti awọn alejo naa si ja fitanfitan lati le figagbaga pẹlu ikọ Plateau United sugbọn pabo lo jasi.

Lọna miran ẹwẹ, asofu fun orilẹede naijiria miran ninu idije CAF Champions League, Akwa United f'idi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu agbabọọlu Banjul Hawks ninu ifẹsẹwọnsẹ ti o waye ni ilu Uyo lọjọ aiku naa pẹlu ami ayo meji si ẹyọ kan.

Related Topics