Chelsea lu West Brom pẹlu ami ayo mẹta s'odo

Victor Moses ndunnu lori ami ayo rẹ pẹlu Chelsea
Àkọlé àwòrán,

Chelsea lu West Brom pẹlu ami ayo mẹta s'odo

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea pada s'oju agbami jija'we olubori ninu idije Premier League pẹlu bi wọn se lu ẹgbẹ agbabọọlu West Bromwich Albion pẹlu ami ayo mẹta si odo ni papa isere Stamford Bridge.

Aseyọri yi waye lẹyin ti Bournemouth ati Watford f'oju Chelsea gbo'lẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn gba sẹyin, eleyi ti o fi jẹ ọran-an yan fun wọn lati jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Eden Hazard lo kọkọ gba bọọlu s'inu awọn fun Chelsea ni isẹju marundinlọgbọn ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, ti Victor Moses si fi ikeji s'inu awọn ki Hazard to tun fi ẹlẹẹkẹta s'inu awọn ni isẹjukanlelaadọrin. Eleyi da ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea pada si ipo kẹrin lori tabili Premier League.

Agbabọọlu iwaju fun orilẹede Naijiria, Victor Moses ti gba bọọlu s'inu awọn fun ẹlẹkeji lati igba ti ifẹsẹwọnsẹ Premier League saa yi ti bẹrẹ. O gba bọọlu s'inu awọn losu to kọja ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye pẹlu Brighton.