Awon Gomina s'agbatẹru fun ọlọpa ipinlẹ

Abdulaziz Yari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn Gomina ti n pe fun akoso ọlọpaa ipinlẹ fun igba diẹ

Alaga ajọ awọn Gomina ni Naijiria (Nigeria Governors Forum), Abdulaziz Yari ti sọ wipe dida ọlọpa ipinlẹ silẹ yoo bojuto eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Yari to jẹ Gomina ipinlẹ Zamfara sọ eyi lẹyin ipade apero ọlọjọ meji ti ile igbimọ asofin agba gbe kalẹ lori eto aabo ni orilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, oni ''awọn se agbatẹru ọrọ ti igbakeji aarẹ, sọ wipe o pọn dandan ki ipinlẹ kọọkan o maa se isakoso awọn ọlọpaa wọn''.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo sọrọ lori anfaani ọlọpaa ipinlẹ kọọkan

Gomina naa sọ siwaju wipe ''iye ọlọpaa ti o wa lorilẹede Naijiria kere si iye awọn eniyan ti o wa lorilẹede yii, eyi to s'afihan ailera awọn ọlọpaa lorilẹede yii".

Nigba ti Yari n sọrọ lori iye owo ti yoo naa awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria lati gbe ọlọpaa ka'lẹ ni ipinlẹ wọn, o wipe "ko pọn dandan fun gbogbo ipinlẹ lati se igbekalẹ yii, sugbọn ki awọn to ba lagbara rẹ o se e".

Ile-isẹ iroyin fun ijọba apaapọ, NAN ranti wipe igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo, nigba se'pade naa lọsẹ ti o kọja, sọrọ lori anfaani to wa ninu ki ipinlẹ kọọkan o sakoso ọlọpaa ti wọn.

Bi ọlọpaa ipinlẹ ṣe n ṣiṣẹ l'America

L'orilẹẹde Amẹrica, ileesẹ ọlọpa ipinlẹ maa n mojuto awọn ohun to niise pẹlu iwadi iwa ọdaran. Isọwọ sisẹ wọn yatọ si ti ọlọpa gbogboogbo ; awọn ni wọn n mojuto igboke-gbodo ọkọ lawọn oju popona to jẹ ti ijọba ipinlẹ, aabo awọn araalu,ipese aabo fun gomina ipinlẹ, to fi mọ eto ẹkọṣẹ awọn to ṣẹṣẹ fẹ ẹ darapọ mọ ileesẹ ọlọpa abẹle, ati ọgbọn atinuda lori imọ ẹrọ ati sayẹnsi.

Yatọ si eyi, wọn tun di alafo nla to wa laarin ọna ti ileesẹ ọlọpa agbegbe ati ti gbogboogbo n gba ṣiṣẹ.

Bakanna ni wọn maa n ṣe iwadi ti wọn naa lori awọn iṣẹlẹ iwa ọdaran. Lara awọn ohun ti wọn maa n ṣe iwadi rẹ ni, awọn ẹgbẹ olokoowo egboogi oloro, awọn onifayawọ ibọn ati awọn ogbontagi ọdaran mi i. Ki iṣẹ wọn le ba so eso rere, awọn ileesẹ ọlọpa ipinlẹ ni i awọn irinṣẹ to ba igba mu to fi mọ awọn akanṣe ibudo ikọṣẹ l'orilẹede naa.

O ti to aadọta ọdun ti wọn ti da ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ. Awọn ohun to niiṣe pẹlu bi awọn araalu ṣe n pọ si, to fi mọ idagbasoke to n de ba awọn ileesẹ lasiko igba naa lo fa a lo ṣe atọkun fun idasilẹ rẹ.

Interview with Col. Hassan Stan Labo (Reitired Colonel)

POINTS:

No better time to start than now.

reasons:

Serious security challenges in nigeria demand establishment of state police

police is better under state management

fg can regulate

no justification for abuse of police by state governors, laws should be passed to watch and guide

top 3 things to do:

1. recruitment process must be thorough and pick the best hands

2. world class training on arms and civility

3. funding for logistics and wages