Fortuna Sittard gba‘sẹ lọwọ Sunday Oliseh

Sunday Oliseh Image copyright Oliseh/Facebook
Àkọlé àwòrán Oliseh ni olukọni to gba ami to pọ julọ laarin awọn olukọni Fortuna Sittard latọdun 1980

Ẹgbẹ Agbabọọlu Fortuna Sittard ti gbasẹ lọwọ olukọni lere bọọlu fun ikọ Super Eagles nigba kan ri, Sunday Oliseh.

Ẹgbẹ naa ni, igbesẹ ọhun waye nitori ihuwasi rẹ sọpọ ẹniyan ninu ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Wọn ni awọn ba Oliseh sọrọ pẹ ko yi iwa rẹ pada, sugbọn ko gbọ.

Ihuwasi Oliseh sawọn alabasisẹp rẹ lo mu ko padanu isẹ rẹ

Fortuna Sittard ni igbesẹ gbigba isẹ lọwọ Sunday Oliseh, kii se nitori isesi ẹgbẹ naa lori papa.

Wọn ni ọun to fa ni bo ti se n wuwa, eleyi ti ko jẹ ki ifọwọsowọpọ wa laarin oun ati awọn alajọsisẹpo rẹ.

Wọn ni "Igbesẹ naa ko dun mọ Fortuna Sittard ninu, bẹrẹ lati ori awọn agbabọọlu, to fi mọ awọn to nbaa sisẹ, sugbọn itesiwaju ẹgbẹ lo se pataki julo"