Champions League: Liverpool rọ'jo goolu sawọn Porto

Sadio Mane Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Sadio Mane ti je goolu mẹfa ninu idije Champions League ọdun yi

Sadio Mane jẹ ami ayo mẹta bi Liverpool ti se fakọyo ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ninu ipele komẹsẹ-o-yọ pẹlu Porto .

Eyi ni igba akọkọ ti Liverpool yoo maa kopa ninu abala idije yi lati nnkan bii ọdun mẹsan sẹyin.

Mane gba goolu alakọkọ sinu awon Porto nigba ti asole Jose Sa kọ lati mu bọọlu ti o fi pẹlẹ gba si ẹgbe kan.

Laipe ni Mohammed Salah jẹwo orukọ rẹ gẹgẹbii ọkan lara awọn atamatase agbabọọlu nilẹ Yuroopu lọwọ yii pẹlu ami ayo ẹlẹkeji tii se ọgbọn goolu ti yoo maa gba wọle ni saa ere boolu rẹ akọkọ pẹlu ikọ Liverpool.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mohammed Salah ti je goolu ọgbọn ninu ifesewonse metadinlogoji fun Liverpool ni saa yi

Pẹlu ayo meji, oun ti opo ro ni pe Liverpool yoo sinmi sugbọn wọn sebi ẹni nsẹsẹ mu ẹyẹ bo lapo ni.

Nigba ti idije naa yoo fi pari, Mane ti jẹ meji sii ti Roberto Firmino naa si gba goolu ikọkanlelogun rẹ ni saa odun yi wọ inu awọn pẹlu.

Ami ayo kẹta ti Mane gba wọle ninu ifẹsẹwọn naa lo sọọ di agbabọọlu ikọ Liverpool keji ti yoo maa gba ayo mẹta wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ kan naa Liverpool idije bọọlu ajumọgba awọn ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Yuroopu lẹyin ti Micheal Owen ti pa iru itu bẹ ni ọdun 2002.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mane gba bọọlu ifẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ naa lẹyin ti o je goolu mẹta

Klopp: oun gbogbo lo lọletoleto fun wa

Akọnimọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ni ''a se dada ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. Bo ti se yẹ la ti se koju awọn alatako wa loni''

Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ pe se isinmi loku nibi ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa, o dahun wi pe ''Rara ko ri be. Oun ti a wa se ni lati mu nkan dẹrun saaju ifẹsẹwọnsẹ keji, a si ti ri se. Ko ju bẹ lọ. Mo ti pẹ ninu isẹ yi lati mo wi pe ojo to rọ ti ko ti daa, Ọlọrun lo mọ iye ẹniyan ti yoo pa.''

Liverpool yoo mura lati pari isẹ ti wọn bẹrẹ nigbati wọn ba gba Porto lalejo ni papa isire Anfield lọjọ kẹfa osu kẹta.

Related Topics