Patrick Pascal: Oliseh jẹ akọni ti ko gba gbẹrẹ

Sunday Oliseh Image copyright @SundayOOliseh
Àkọlé àwòrán Oliseh lori papa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Fortuna Sittard

Onimọ ijinlẹ nipa ẹrẹ bọọlu,Patrick Pascal ti o figba kan sisẹ pẹlu Sunday Oliseh ti nsọ iriwisi rẹ lori bi ẹgbẹ agbabọọlu Fortuna Sittard ti se pasẹ lo rọkun nile fun akọni naa.

Lọjọ ojọọru ni ẹgbẹ agbabọọlu na fi atẹjade sita pẹ ki Sunday Oliseh lọ ọ sinmi nile nitori pẹ ibasepọ laarin oun ati awọn alabasisẹpọ rẹ ko danmoran.

Sugbọn ninu esi rẹ si isẹlẹ naa, Oliseh fi ọrọ sita lori oju opo twitter rẹ pẹ bi oun ti se ko lati kopa ninu iwa ti ko to lo sokunfa asẹ lorọọkun nile ti wọn pa.

Agbiyanju lati ba Sunday Oliseh sọrọ lori oun ti o pe ni ''iwa ti ko tọ'' sugbọn pabo lo jasi.

Patrick Pascal to sisẹ pẹlu Oliseh nigba kan ri salaye pẹ orisirisi ipenija ni akoni a ma foju ba ninu ẹgbẹ agbabọọlu.

O ni ọpọ igba ni akọni ati awọn to gba sise a ma ni ede aiyede lori orisiri nnkan.''Aigboraeniye a ma sẹlẹ lori bi akọni ti se fẹ se eto lori papa.Eyi a ma wayẹ lọpọ igba''

Pascal ni Sunday Oliseh ti oun mo dada ki se akọni to gba gbẹrẹ laaye yala lati ọdọ awọn agbabọọlu rẹ tabi lọdọ awọn to ni ẹgbẹ agbabọọlu.

''Bi Oliseh ba so wi pe oun koni se nnkan,ko wọpọ ki o yi ohun pada.Eleyi le jẹ ara nnkan to'n fa ede aiyede laarin wọn''

Mutiu Adepoju:Akọni gbọdọ je ẹni to ni suuru

Ninu ọrọ ti re,ogbontarigi agbabọọlu fun Super Eagles nigba kan ri, Mutiu Adepoju ni isẹ akọni ki se isẹ to rorun.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIfọrọwanilẹnuwo pẹlu Mutiu Adepọju

O ni oun ko le sọ nipa Oliseh ju wi pẹ awọn jijọ gba bọọlu ni igba kan ri fun Super Eagles.

Ibasepo ''wa ko si ju wi pe akegbe niwa lori papa.''