Fortuna Sittard tako Oliseh pe wọn tapa sofin

Sunday Oliseh ati awọn agbabọọlu rẹ lori papa Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Osu kejila ọdun 2016 ni Sunday Oliseh gba isẹ olukọni agba fẹgbẹ agbabọọlu Fortuna Sittard

Ẹgbẹ agbabọọlu onipele keji torilẹede Holland, Fortuna Sittard, ti lodi sọrọ Sunday Oliseh, to ni wọn ni ki oun lọsinmi nile na nitori pe oun kọ lati kopa ''ninu awọn igbese ti ko tọna.''

Won pasẹ pe ki Oliseh lọ rọọkun nile na lọjọru, lori esun iwa ti ko tọ.

Ninu idahun rẹ, o sọ wipẹ, ẹ́gbe agbabọọlu naa fẹ ki oun "tapa s'ofin".

Ninu atejade kan to fisita lojobo, ẹgbẹ agbabọọlu naa so wi pe, awọn yoo gbe Oliseh lo ile ẹjọ ati wipe o seese ki awọn gba'sẹ lọwọ rẹ.

Champions League: Liverpool rọ'jo goolu sawọn Porto

Patrick Pascal: Oliseh jẹ akọni ti ko gba gbẹrẹ

O seese ki Fortuna Sittard gbe Oliseh lọ sileẹjọ

Ẹgbẹ agbabọọlu naa ni: "Ọrọ ti Oliseh so ko jo pe awa lo'n ba wi."

"A o gbe ẹjọ naa losi iwaju igbimọ alatunto fun ajọ elere bọọlu nilẹ Holland eyi ti kii gbe lẹyin ẹnikeni. Awon ni yoo wa fi aridaju han boya a le gba ise lọwọ Oliseh.''

Won yan Oliseh sipo olukọni agba fẹgbẹ agbabọọlu naa lọdun 2016.

Related Topics

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí

Àwọn ojú òpó ayélujára tí ó jọ èyí

BBC kò mọ̀ nípa àwọn nnkan tí ó wà nínú àwọn ojú òpó ayélujára ní ìta