Ẹni to ni Portsmouth tẹlẹ rẹwọn lori owo iyawo rẹ to ji

Al Fahim
Àkọlé àwòrán Al Fahim(apa ọtun) dari Portsmouth fun ọsẹ maarun ni 2009

Wọn ti ju ọkunrin to ni ẹgbẹ agbabọọlu ti Kanu Nwankwo gba bọọlu fun, laarin ọdun 2006 si 2012 sẹwọn.

Ọkunrin naa to ni Portsmouth fun ọsẹ marun, lasiko ti laluri de ba Portsmouth lọdun 2009, ni wọn ju sẹwọn ọdun marun nilẹ United Arab Emirates nitori wipe o ji miliọnu maaru pọun, to jẹ ti iyawo rẹ lati ra ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Sulaiman Al Fahim, to lewaju ileeṣẹ Abu Dhabi ninu idunadura lati ra Manchester City lọdun 2008, ni wọn tun ri wip,e o jẹbi ẹsun iwe yiyi, to fi mọ lilo awọn ayederu iwe akọsilẹ, o si tun se atilẹyin fun iwa ibajẹ.

Aṣiri oun ati isọmọgbe rẹ tu wipe wọn ji owo ti wọn fi ra Pompey lati ọwọ Sacha Gaydamak, ki Al Fahim tun to ta ẹgbẹ agbabọọlu naa fun Ali Al Faraj.

Al Fahim, ẹni ọdun mejilelogoji, kọ lati lọ si ibi igbẹjọ naa, ile ẹjọ si da ẹjọ rẹ lai fi igbesẹ rẹ naa ṣe.

Osu marun pere ni Al Fahim fi ni Portmouth

Awọn arojọ takoni kan sọ pe iyawo Al Fahim sakiyesi pe, owo naa ti poora lẹyin ti ele to yẹ ko gun ori owo to fi pamọ si ile ifowopamọ kan to ṣi lọdun 2009 ko wọle.

O sọ wipe oun kan si alamojuto apo aṣunwọn naa, ṣugbọn nṣe loun fi ọrọ naa falẹ.

Igba to pinnu lati lọ si ile ifowopamọ naa, ni wọn sọ fun wipe ko si owo kankan ninu apo aṣunwọn naa.

Lẹyin eyi lo lọ si ẹka to wa fun ọrọ ofin nile ifowopamọ naa lati fi to wọn leti, ṣugbọn nigbati wọn kuna lati gbe igbesẹ kankan lori ọrọ naa, lo mu ẹjọ lọ si ileeṣẹ ọlọpa.

Ile ẹjọ to ngbẹjọ iwa ọdaran n'ilu Dubai tun ṣe idajọ lori alamojuto ile ifowopamọ naa, fun ẹsun afọwọra, iwe yiyi, to fi mọ ṣisẹ amulo awọn iwe akọsilẹ ti wọn yi.