Chelsea na Hull City ni 4-0 ninu idije FA Cup

Aworan agbabọọlu Willian to wẹ yan kainkain ninu ifẹsẹwọnsẹ naa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Willian ni agbabọọlu to wẹ yan kainkain ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu ọpọlọpọ ege ati ete to oun ti bọọlu meji to jẹ

Olivier Giroud ati Willian ran Chelsea l'owo lati f'agba han Hull City ni ifẹsẹwọnsẹ to mu ẹgbẹ naa wọ ipele ikeji ipele asekagba idije FA Cup.

Olukọni ẹgbẹ naa, Antonio Conte, sọ wipe awọn agbabọọlu naa ti fun oun ni "iya meji to dara" nipa ikọ ẹgbẹ naa ti yoo k'oju Barcelona l'ọjọ isegun.

Willian wẹ yan kainkain ni ninu ere bọọlu ti wọn gba pẹlu Hull City, oun si ni ẹni to koko gba bọọlu wọ inu awọn ẹgbẹ agbabọọlu naa to wa lẹyinlẹyin ninu idije Championship.

Pedero lo jẹ bọọlu keji nigba to sare gba bọọlu si abe David Marshal kete ti Cesc Fabrigas gba bọọlu si.

Lẹyin igba naa ni Willian jẹ bọọlu ẹlẹkeji nigba ti oun ati Giroud gba bọọlu si'rawọn.

Atamatase orilẹede France,Oliver Giroud, si jẹ bọọlu akọkọ fun Chelsea lati igba to ti kurọ ni Arsenal lẹyin igba ti Emerson Palmieri gba bọọlu si oju ile Hull City lati apa alafia.

Related Topics