Idije Olympics: Wọn n ṣe iwadi Alexander Krushelnitsky

Alexander Krushelnitsky Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Wọn ti fẹsun lilo ogun oloro kan Alexander Krushelnitsky

Ile ẹjo to'n gbọ ẹsun gbogbo to jọ mọ ere idaraya ti bẹrẹ ẹjo pẹlu oludije ọmọ orilẹede Russia Alexander Krushelnitsky lori ẹsun lilo oogun oloro.

Krushelnitsky ti oun ati iyawo rẹ ṣe ipo kẹta gba ami ẹyẹ baba (bronze) ninu idije Olympics lọdun 2018 ni wọn fura si wipe o lo oogun oloro kan ti orukọ rẹ njẹ meldonium.

Ajọ to n ṣakoso ere idaraya olympics lo ṣokunfa mimu ẹsun naa ba ọmọ ọdun mẹẹdọgbọn ọhun.

Wọn ti dajọ sọna fun ipẹjọ naa wọn si nreti ayẹwo ẹjẹ rẹ lọjọ aje.

Agbẹnusọ fun ajọ to n ṣakoso ere idaraya olympics (IOC) ni ''yoo jẹ oun ibanuje fun wa ti wọn ba fidi ẹjọ mulẹ lori iṣẹlẹ yi''.

Atẹjade kan lati ajọ naa fi kun un wi pe "lilo oogun oloro, ayẹwo ṣiṣe ati fifi iya jẹ awọn to ba lodi s'ofin ninu ere Olympic Winter Games Pyeongchang 2018 jẹ oun to wa lọtọ si ajọ to n ṣakoso ere idaraya olympics (IOC).