Ẹgbẹ agbabọọlu Kano Pillars padanu Chinedu Udoji

Chinedu Udoji Image copyright Kano Pillars/Facebook
Àkọlé àwòrán Chinedu Udoji

Ẹgbẹ agbabọọlu Kano Pillars ti kede iku ogunna gbongbo ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu wọn kan, Chinedu Udoji.

Ninu atẹjade kan lori opo ibanisoro facebook wọn, wọn wipe Chinedu Udoji padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ kan to sẹlẹ loju ọna Club nilu Kano.

A gbọ wipe o'n dari bọ lati ọdọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ nigbakan ri ninu ẹgbẹ Eyimba to ṣe abẹwo si.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Chinedu Udoji ninu ọkan lara awọn ifesewonse to kapa fun Kano Pillars

Ọrọ Pataki nipa rẹ:

  • Udoji darapọmọ Eyimba lọdun 2009
  • O lo saa maarun nipo Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Eyimba
  • O gba ife ẹyẹ league meji pẹlu Eyimba
  • Bakanna lo gbe ikọ rẹ de abala to kangun si aṣekagba idije CAF Champions League
  • Lọdun 2016 lo darapọ mọ Kano Pillars.

Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ nigba kan ri, Eyimba ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi akinkanju balogun ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Ninu ọrọ rẹ lori iku Chinedu, Felix Anyansi Agwu to jẹ alaga ẹgbẹ Eyimba ni ọlọyaya ni lori papa ati laarin awọn akẹgbe rẹ naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Related Topics