West Brom: Awọn agbabọọlu sa fun igbẹjọ ẹsun ole

Gareth Barry, Jonny Evans, Jake Livermore ati Boaz Myhill Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gareth Barry, Jonny Evans, Jake Livermore ati Boaz Myhill ti kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ere bọlu n'igba 1,236

Awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu West Brom mẹrẹẹrin ti wọn fi ẹsun kan wipe wọn ji ọkọ takisi kan gbe n'ilu Barcelona, ti ngbaradi lati sa nile ẹjọ nitori pe ko si ẹri ni wọn se bẹẹ.

Biotilẹjẹpe ileeṣẹ ọlọpa fi ọrọ wa Gareth Barry, Jonny Evans, Jake Livermore ati Boaz Myhill l'ẹnu wo, sibẹ wọn ko fi panpẹ ofin gbe wọn, ko to di wipe wọn gbe ẹjọ naa lọ siwaju ile ẹjọ ibilẹ kan.

Wọn ti da ẹjọ naa nu fun igba diẹ, ṣugbọn o ṣeeṣe ki wọn tun pada bẹrẹ igbẹjọ ọhun bi ẹri tuntun ba fi f'ojuhan.

Ẹgbẹ agbabọlu West Brom naa ti bẹrẹ iwadi tiwọn lori iṣẹlẹ ọhun to waye lọjọbọ.

Barry, Evans, Livermore and Myhill tọrọ aforiji lọjọ ẹti fun pe "wọn tapa si ofin konile o gbele ẹgbẹ agbabọọlu naa ati fun awọn iṣẹlẹ to ti ta epo si aṣọ aala rẹ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Mossos d'Esquadra - olori ileeṣẹ ọlọpa l'ẹkun naa, ninu ọrọ kan to ba BBC sọ ṣaaju ni, awọn mẹrẹẹrin fẹ naju lọ ni Barcelona, sugbọn wọn ri wipe ita ti da paro, nitori eyi ni wọn ṣe wọ takisi kan lọ si ile ounjẹ igbalode kan ti wọn kii tilẹkun rẹ tọsan-toru.

Nigba ti wọn kuro nibẹ ni aago marun abọ idaji, wọn fi ẹsun kan wọn pe, wọn gbe ọkọ takisi naa, wọn si i wa a lọ si ile itura wọn laisi awakọ naa nibẹ.

O seese ki Adajọ tun nse agbende ẹsun naa

Awọn onile itura ati awakọ naa lo pe awọn ọlọpa, ko to di wipe o gba ọkọ rẹ ni nnkan bi aago mẹjọ aarọ.

Wọn ti kesi adajọ ile ẹjọ ibilẹ naa lati f'oju wo o boya ẹri to peye wa lati fi ẹsun "ole jija" kan wọn.

West Brom, to wa ni isalẹ tabili Premier League, ti wa nibudo igbaradi lorilẹede Spain.

Nigba toun sọrọ lẹyin ti Southampton na wọn m'ọle pẹlu ami ayo meji s'oodo lọjọ abamẹta, akọnimọọgba wọn , Alan Pardew ni "inu n bi oun si awọn mẹrẹẹrin."