Wigan f'opin s'irinajo Man City ninu idije FA Cup

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wigan f'opin sirinajo Man City ninu idije FA Cup
Ẹgbẹ agbabọọlu Wigan Athletic ti fi opin si irinajo ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ninu idije ife ẹyẹ FA Cup.
Manchester City f'idi rẹ'mi pẹlu amin ayo ẹyọ kan si odo ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lalẹ ọjọ aje.
Itumọ ijakulẹ yii fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ni pe ireti wọn lati gba ife ẹyẹ mẹrin ni saa yii ko lee ṣeeṣe mọ.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wigan Athletic wa ni ipele keji ninu ikọ bọọlu gbigba nilẹ Gẹẹsi
Will Grigg gba ayo kan ṣoṣo ti o wa ninu idije naa wọle, eyi ti awọn ikọ Pep Guardiola ko lee da pada lẹyin ti wọn dinku si eniyan mẹwa ni ipele akọkọ.
Pẹlu ijakulẹ ọjọ aje, Manchester City yoo lee gbajumọ ife ẹyẹ Premier League nibiti wọnti n se ipo kini lọwọlọwọ.
Manchester city yoo maa waako pẹlu ikọ Arsenal ninu aṣekagba idije Carabao Cup.